Àwọn ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa Ìjàpá Ogbomoso kó tó kú

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Lẹ́yìn tí Ijapa to dagba ju nilẹ Afirika yii dagbere faye lẹni ọdun mejilelọọdunrun, ile iṣẹ BBC ṣewadii awọn nkan to laami laaka nipa rẹ.

Gẹgẹ bí awọn akọṣẹmọṣẹ atawọn onimọ nipa itọju ẹranko ṣe sọ ọ, aaringbugbun gbekede ti ijapa n lo laye ni aadọjọ ọdun bẹẹ si ni eyi ti eeyan ti ri ri to ju bẹẹ lọ ṣaaju ti Alagba ni o lo Igba ọdun laye.

Ẹwẹ, Alagba ṣe o lo odidi ọdun mejilelọọdunrun loke eepẹ ko to faye silẹ.

Lara ohun ti ẹ ko mọ nipa oloogbe ijapa to wa lafin Ṣọun Ogbomoso ree.

Agba Inaki n ṣe'daro Alagba

  • Ijapa Ogbomoso dagba ju gbedeke iye ọjọ ori tawọn onimọ ni o yẹ ki Ijapa kan lo laye lọ.
  • Wọn ko gun un ni abẹ́rẹ́ ri tabi ki awọn onimọ iṣegun oyinbo ṣe ayẹwo fun un ri.
  • Ẹẹmeji pere ni Alagba maa n jẹun laarin oṣu kan kii sii sunmọ ẹnu ibode ọgba rẹ ayafi bo ba fẹ mu omi. Eyi ni wọn fi n mọ pe omi lo fẹ.
  • Awọn eeyan a ma lọ sọdọ ogbologbo Ijapa yii lati tọrọ ẹbẹ adura to si n wa si imuṣẹ

Àwọn àrídájú 'ọ̀rọ̀ yìí wá látẹ́nu akọ̀wé àgbà Toyin Ajamu ní ààfin Kábíyèsí Ṣọun ti ilu Ogbomosho fún BBC Yorùbá.