Ìjàpá tó wà ni ààfin Ṣọ̀ún Ogbomọṣọ ti jáde láyé lẹ́yìn to ti lo 344 ọdún láyé

Ijapa to wa ni afin Ogbomọṣọ to ti lo ojilelọọdunrun o le mẹrin ọdun loke eepẹ ti jade laye.

Toyin Ajamu, to jẹ akọwe agba ni Àafin Kabiyesi Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ sọ fun bi BBC pe, ijapa naa ti apele rẹ n jẹ Alagba jade laye lẹyin aisan ranpẹ.

O ni nkan bi aago mọkanla abọ owurọ yii ni ọba tọ ọlọjọ lọ.

Ajamu ṣalaye pe, idi ti wọn fi n pe ijapa ọhun ni Alagba jẹ nitori ọjọ ori rẹ.

O tẹsiwaju pe erongba ilu Ogbomọṣọ ni lati gbe iyoku ara ijapa ọhun si gbagede, ti gbogbo eeyan yoo si le ma wo nilẹ yi ati loke okun.

Ajamu ni ijapa naa ti gbe ni afin Ṣọun fun ọpọlọpọ ọdun, to si ni awọn osiṣẹ afin Ogbomọṣọ to ma n toju rẹ ki ọlọjọ to de.