You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Minimum Wage: Chris Ngige fèsì lórí ìyànṣẹ́lódì tí àwọn òṣìṣẹ́ fẹ́ gùnlé
Minisita fun ọrọ osisẹ ati igbanisisẹ, Chris Ngige ti ni adinku yoo ba awọn osisẹ lorilẹede Naijiria ki ijọba le san owo osu awọn osisẹ.
Nigige sọ eyi fun awọn adari ajọ osisẹ, NLC ni Abuja lasiko ti wọn se abẹwo si i.
O ni ọọdunrunlelọgọrin biliọnu Naira ni ijọba nilo lati le fi san gbedeke owo osu awọn osisẹ, eleyii to ni o soro fun ijọba lati san pẹlu ọrọ aje to dẹnukọlẹ.
Amọ, awọn osisẹ ti fariga o, pe onyẹ kan ko gbọdọ yẹ gbedeke owo osu osisẹ.
Ọjọkejidinlogun, Osu Kẹrin ni Aarẹ Muhammadu Buhari bu ọwọ lu ofin to rọ mọ igbeleke owo osu osisẹ.