You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
#BBCGovDebate: Sanwo-Olu, Jimi Agbaje yọ kúrò nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ìtagbangba BBC ní Eko
Lẹ́yin-o-rẹyin, eto ijiroro itagbangba ileeṣẹ BBC yoo waye ni ọjọ abamẹta ni ipinlẹ Eko.
Awọn oludije marun ni o yẹ ko kopa ninu eto ọhun ṣugbọn awọn oludije fun ipo gomina ipinlẹ Eko labẹ aṣia ẹbẹ oṣelu APC, Babajide Sanwo-olu ati ẹgbẹ oṣelu PDP Jimi Agbaje ko ni kopa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gbogbo ọna to yẹ ni yiyẹ ni ileeṣẹ BBC gba lati rii pe awọn mejeeji yii kopa ṣugbọn lẹyin-o-rẹyin awọn mejeeji yii ni awọn ko ni lee kopa ninu ijiroro itagbangba naa.
Amọṣa, awọn oludije ti yoo kopa bayii ni Babatunde Gbadamọṣi ti ẹgbẹ oṣelu ADP, Ọmọlara Adesanya fun ẹgbẹ oṣelu PPC, Olumuyiwa Fafowora ti ẹgbẹ oṣelu ADC ati Adebisi Ogunsanya YPP.