You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Amotekun: Àwọn aṣòfin ilẹ̀ Yoruba yóò ṣe ìjíròrò ìta gbangban lórí àbádòfin lọ́jọ́ Ajé
Gbogbo ile igbimọ aṣofin lawọn ipinlẹ Yoruba ni Naijiria ti ṣe tan lati ṣe ijiroro ita gbangba lori eto ikọ alabo Amotekun.
Agbarijọpọ awọn agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Ekiti, Osun, Oyo, Ogun ati ipinlẹ Eko lo fi ọrọ naa lede.
Nibi ipade kan to waye nilu Ibadan lọjọ Kẹrinla Oṣu Keji ọdun 2020 ni wọn ti sọ pe ijiroro ita gbangba naa yoo waye.
- Aláàfin ìlú Oyo, Ikú Bàbá Yèyé tún bímọ tuntun làǹtì lanti
- Òṣèré tó kópa nínú fíímù Queen of Katwe, kú lọ́mọ ọdún 15
- Ọkọ'yàwó jẹ àjẹranjú ìyà lẹ́yìn tí ìyàwò rẹ̀ yọjú síbi ìgbéyàwó òun àti obìnrin mìràn
- 'Iná tó n jó àwọn ọjà l'Eko kìí ṣe ojú lásán'
- Torí ǹkan oṣù, Iléèwé pàṣẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tú síhòhò
Awọn agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin naa ṣepade lọjọ keji ti awọn Gomina ipinlẹ wọn ṣepade pẹlu ọga agba ajọ ọlọpaa ni Naijiria nipinlẹ Eko.
Awọn eeyan ọhun fẹnuko lati ṣepade pẹlu awọn adajọ agba nipinlẹ wọn lẹyin ijiroro naa, lati lee ṣayẹwo agbekalẹ abadofin naa.
Ninu atẹjade ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin ni wọn ti sọ pe "Lẹyin ọpọ ijiroro ni a fẹnuko pe gbogbo ile igbimọ aṣofin nilẹ Yoruba ni lati gbe igbesẹ ati fi Amotekun sinu ofin ipinlẹ wọn."
Wọn tẹ siwaju pe "A ti kan nipa fun gbogbo ilẹ igbimọ aṣofin ilẹ Yoruba lati ṣe ijiroro ita gbangba nigba kan naa ni awon ipinlẹ wọn lọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji ọdun 2020."
Bẹẹ ni wọn wa rọ awọn ara ilu lati peju sibi ijiroro ita gbangba ọhun lati le dasi ọrọ abo gbegbe wọn.
Wọn ti wa parọwa si ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo to wa ni isinmi lati pada sẹnu isẹ, ki wọn le ṣeṣẹ lori ababdofin ọhun.