3rd Mainland Bridge: Mo fẹ́ lọ tọ̀ l'ọkùnrin tó bẹ́ sódò so fún awakọ̀

Igbiyanju lati doola arakunrin to bẹ si ọsa lati ori afara Third Mainland Bridge nilu Eko ti wa si opin.

Ohun ta gbọ ni pe arakunrin naa sọ fun awakọ to gbe wi pe oun fẹ tọ afi bo ṣe bọ silẹ ninu ọkọ ti o si bẹ sodo.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa nilu Eko sọ, iṣẹlẹ naa waye ni nkan bi ago mọkanla owurọ ti gbogbo awọn oṣiṣẹ pajawiri si pawọpọ lati doola ẹmi rẹ.

Ki ni ohun ta mọ nipa arakunrin to bẹ sodo naa

Gẹgẹ bi ohun tajọ iṣẹlẹ pajawiri nilu Eko,LASEMA sọ, wọn ni orukọ arakunrin naa ni Daibo Toju Davies ti ọjọ ibi rẹ si jẹ ọjọ kejilelogun oṣu Keje ọdun 1998.

Wọn fi kun pe o n gbe ni ojule kẹtadinlogun ni opopona Sosanya,Gbagada Soluyi nilu Eko.

Lasema sọ pe lati ile iwosan Mercy Hospital ni Gbagada ni arakunrin naa ti wọ ọkọ Uber ki o to de ori afara Third Mainland ti o si bẹ sodo.

Wọn ni iwaadi awọn fi han pe arakunrin naa sọ fun awakọ Uber to gbe pe inu n run oun.

Kete ti awakọ duro, lo ba bẹ sodo.

Agbarijọpọ ajọ iṣẹlẹ pajawiri ati ileeṣẹ panapana ilu Eko ni wọn jijọ gbiyanju lati doola ẹmi arakunrin naa.