You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Marriage by Election:Àwọn ọkùnrin méjì kópa nínú ìdìbò láti yan ọkọ fún ọmọ ọdún mẹ́rìnlá
Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo de ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹ.
Bẹẹ lọrọ ri pẹlu omidan kan, ọmọ ọdun mẹrinla,Hajara, ẹni ti iporuru ọkan ba nipa ẹni ti yoo fẹ laarin awọn ọkunrin meji to lawọn fẹ fi ṣe aya.
Nigba ti Hajara ko mọ boya ki oun gba fun Ibrahim tabi Yunusa lo ba ni ki wọn lọ kopa ninu idibo ti o si ni ẹni ba jawe olubori loun yoo fẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọkọ'yàwó jẹ àjẹranjú ìyà lẹ́yìn tí ìyàwò rẹ̀ yọjú síbi ìgbéyàwó òun àti obìnrin mìràn
- Iléẹjọ́ wọ́gilé ìgbeyàwó nílànà ẹ̀sìn Islam pé kò bófin mu
- Aṣọ ń pe aṣọ ráńṣẹ́ láàrin àwọn òṣèré tíátà ní àyájọ́ olúlùfẹ́
- Gbogbo ẹ̀yin ọ̀ba abẹ́ mi, tí ẹ̀ ń ta ilẹ̀ ìlú, ẹ kò ní fara re lọ - Oluwo
- Ìjọba Ọ́ṣun, Oluwo kò yẹ lẹ́ni tó leè darí ìlú, ẹ bá wa le kúrò lórí ìtẹ́ - Olú ti Ilé-Ogbó
Isẹlẹ naa, to waye nilu Giade nipinlẹ Bauchi lo n se ọpọ eeyan ni haa-hii.
Akọroyin wa to ba Hajara ati ẹgbọn rẹ ọkunrin sọrọ sọ pe awọn ọkunrin mejeeji naa, ti ọjọ ori wọn naa ko to ogun ọdun, ni ko setan lati fi Khadijah silẹ, lọrọ ba di taa ni iyawo ọsingin yoo ja mọ lọwọ.
Bi idibo naa ti ṣe lọ
Awọn mejeeji gba lati kopa ninu idibo eleyi ti arakunrin kan Umar Saleh dari rẹ.
Ki wọn to bẹrẹ idibo ni wọn ti yan igbimọ ti yoo gbẹjọ kotẹmilọrun to ba waye latara idibo naa.
Idibo naa waye ni iwajuile Yunusa to jẹ ọkan lara awọn arakunrin to fẹ gbe Hajara ni iyawo.
Hajara ran awọn ọrẹ rẹ lati lọ wo bi idibo naa ti ṣe lọ ti o si pada ja si pe Yunusa bori Ibrahim to jẹ alatako rẹ.
Ibrahim fariga, o kọ esi dibo naa
Lọjọ ti idibo waye, se ni ero pe pitimu, to fi mọ awọn ọmọde ati agba,koda awọn oṣiṣẹ ajọ orilalakanfisọri naa peju sibẹ.
Lẹyin idibo naa, ti Inusa bori, ni wọn ba ja iwe ajakọ kan, ti wọn si fun niwe ẹri moyege ibo, pe o lasẹ lati fẹ Hajara.
Ọrọ yi gẹgẹ bi akọroyin wa ti ṣe wadi ko dun mọ Ibrahim ninu ti o si fi ẹhona han nitori pe iwaju ile Yunusa ni idibo ti waye.
Ọrọ ti a ni ki baba ma gbọ, baba naa lojọ pe yoo pada ba wọn pari rẹ
Ọrọ ti lọ si ọdọ baalẹ ilu naa ti ṣe Mohammad Sabo Abdulkadir.
Ibi ti baalẹ ba yanju ọrọ si ni yoo sọ ẹni ti yoo pada fẹ Hajara.
O ṣeeṣe ki awọn mọlẹbi ti ọrọ kan pada jiroro lati yanju ọrọ yi ni tubinubi tabi ki wọn tun ibo di.
Bi o ba ṣa tiṣe ri, Hajara ti sọ pe ẹni ti wọn ba sọ pe o yege ni oun yoo fẹ.
Eyi si lo mu ki o di ọkọ iyawo, ni oloruka ba gba oruka, ti ọwọ awe keji si gbofo.