You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP sí Buhari: Gbájú mọ́ ìṣèjọba rẹ ní, yé dùnkokò mọ́ alátakò àti oníròyìn
Ẹgbẹ alatakọ lorileede Naijiria Peoples Democratic Party ti sọ fun aarẹ Muhammadu Buhari pe ki o duro nibi ti wọn ba fi ẹlẹmọṣọ rẹ sọ ko ye dunkoko mọ alatako.
Ikilọ ti wọn fi sita yi ninu atẹjade kan ko sẹyin bi ileeṣẹ aarẹ ti ṣe ni awọn alatako ati awọn oloṣelu kan n pete lati ṣe iwọde kan lọjọ Aje.
Kola Olongbọdiyan to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa lo fi ọrọ yi sita loju opo Twitter.
Ologbọndiyan sọ pe ọrọ ti d'eti igbọ ẹgbẹ PDP pe ijọba Buhari n wa ọna lati doju ọrọ ru lori ailekoju ipenija agbesunmọmi, awọn janduku ajinigbe ati awọn ikọlu miran to n peleke sii ni Naijiria.
''O ti han si gbogbo eeyan to fi mọ ijọba Buhari pe awọn ọmọ Naijiria n tako ijọba rẹ ti wọn ko si nilo ẹnikẹni lati ko wọn jọ ki wọn to fẹhonu han''.
Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa sọ bakanna pe''ọna lati dunkoko mọ wa lati ma ṣe beere pe ki ijọba ji si awọn ojuse rẹ ni wọn n da. A ko si ni gba''
Lọjọ Abamẹta ni Garba Shehu to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ aarẹ Naijiria figbe ta pe awọn oloṣelu kan ati awọn to n jẹ nidi ikọlu BokoHaram ti ṣeto awọn ayederu oluwọde to to ẹgbẹrun meji ti yoo fi ẹhonu han tako awọn olori ọmọogun Naijiria lọjọ Aje.
Garba Sheu to darukọ ẹgbẹ PDP ninu ọrọ rẹ sọ pe ọna ati tabuku ba aarẹ Buhari ni wọn da ti wọn si fẹ ki araye ro pe awọn ọmọ Naijiria wa lẹyin wọn.