LASEMA dáwọ́ wíwá ọkùnrin tó bẹ́ s'ódò 3rd Mainland Bridge dúró

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti so wiwa ọkunrin to bẹ sinu odo afara 3rd Mainland Bridge l'Eko rọ na.

Loru ọjọ Satide ni aj LASEMA ṣe ipinu yii ti wọn si ni idi ti awọn fi ṣe bẹẹ ni tori ọwọ iji omi naa.

Awọn adoola sọ pe bi omi naa ṣe n fi sihin sọhun ko jẹ ki awọn le tete ri arakunrin naa lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti wa ninu omi.

Eyi lo mu ki ajọ LASEMA sun wiwa ọkunrin naa siwaju di ọjọ aje.

Iroyin sọ pe ṣe ni ọkunrin ọhun sọ fun dẹrẹba Uber to gbe e pe oun fẹ tọ, afi ti o bọọlẹ ninu ọkọ to si fo sinu alagbalugbu omi.

Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko jẹ ko di mimọ iṣẹlẹ naa waye ni nkan bii agogo mọkanla owurọ ti gbogbo awọn oṣiṣẹ iṣẹlẹ pajawiri atawn adoola si ti ṣe asugba lati tete doola ọkunrin naa.

Nipa Ọkunrin naa

Daibo Toju Davies ni arakunrin naa n jẹ ti wọn bi i ni ọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 1998 gẹgẹ bi ajọ LASEMA ṣe sọ ọ.

Wn fi kun un pe ojule nọmba ikẹtadinlogun adugbo Sosanya ni Gbagada Soluyi ni o n gbe ni ilu Eko.

Pẹlu iwadii wọn, wọn ri i pe arakunrin hun sọ fun awakọ to gbe e pe inu n lọ oun. Lẹyin ti awakọ duro lo sọkalẹ to si fo afara bọ sinu odo.

Ajọ́ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri l'Eko, LASEMA, ile iṣẹ panapana atawọn adoola oju omi lo wa nikalẹ lakoko naa lati doola rẹ̀.