Lagos Okada ban: 'Ọ̀kadà gígùn ni mo fi bọ́ ọmọ àti ìyàwó'
Ọwọ to dilẹ, l'Eṣu maa n bẹ ni iṣẹkiṣẹ. Eyi ni ọrọ ọkan lara awọn ọlọkada niluu Eko, Oladejo Adetunji lori igbesẹ ijọba lati fofin de alupupu ti ọpọ mọ si ọkada ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta.
Ṣaaju ọjọ kinni oṣu keji ọdun 2020 ti eto naa yo gbera sọ, Ọgbẹni Adetunji sọ pe ofin ti ijọba gbe kalẹ yii dabi ẹni pe ijọba gba ẹmi lẹnu awọn ni.
O ṣalaye pe ko si ọna mii ti oun mọ lati fi wa ounjẹ ọjọọ ti oun yoo fi bọ idile oun, ati wi pe ijọba gan an ko pese iṣẹ miiran fawọn ko to fofin de ọkada gigun.
Ọgbẹni Adetunji rọ ijọba lati tun ero rẹ pa lori igbesẹ rẹ ki o si wa ọna mii ti yoo mu irọrun ba awọn ara ipinlẹ Eko.
- Ọmọ Yahoo yóò pọ̀ si tẹ bá ní kí ọ̀kadà má rìn lójú pópó Eko - Àwọn ọ̀dọ́
- Okada Ban: ọjọ kini oṣù keji ni òfin tuńtun yóò bẹ̀rẹ̀
- Uber ni mo fẹ́ máa gbé báyìí, mi ò tún fẹsẹ̀ rìn mọ́ - Agunbaniro to n gba N33,000
- Bí Favour ṣe sùn, mo gbá ọmọ odó mọ́ ọ lórí a sì gé orí, ọkàn àti ọyàn rẹ̀ fún àsèjẹ - Kayeefi
- Wo iye ibùdó ìtójú ibà Lassa tó wà ní Nàìjíríà
- "Ọlọ́pàá ní kí n bọra sílẹ láti mọ bóyá obìnrin ní mí torí mo ní irùngbọ̀n"