Oloye Akin Alabi: Ìdí tí a fí takò lílo N37b láti fi tún Ilé Aṣòfin Àpapọ ṣe

Oríṣun àwòrán, @others
Asojusofin mẹta lo ti bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ ijọba lati lo biliọnu mẹtadinlogoji lati fi se atunse Ile Igbimọ Asofin apapọ ni ilu Abuja .
Eyi ko ṣẹyin bi Ile Igbimọ Asofin se gbe jade ninu eto isuna fun ọdun 2020 wi pe wọn yoo nilo owo yii lati tọ̀'ju Ile Igbimọ Asofin.
Ni oju opo Twitter ni Asojusofin Oloye Akin Alabi, Ochilegor Idagbo ati Bamidele Salam ti sọrọ tako igbeṣẹ wọn yii.
Wọn fikun wi pe ki wọn lo owo naa lati fi pese ile iwosan fun awọn eniyan, idokowo kekeeke ati ohun amayedẹrun miran fun awọn ọmọ Naijiria.
Oloye Akin Alabi sọ pe o dara ki ijọba apappọ na owo naa lati fi ṣe atunsẹ awọn ile iwosan ati ile wa ju ki wọn na owo naa fun atunsẹ Ile Igbimọ Asofin apapọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bamidele Salami naa ko gbẹyin ni bi o ṣe bu ẹnu atẹ lu eto iṣuna ọhun.
- Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019
- Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà
- Lórúkọ ìdílé Diya, a gbúdọ̀ ti ẹsẹ̀ òfin bọ ìkú tó mú ọkọ àti ọmọ méjì lọ - Agbẹjọ́rò
- Ojú ayé lásán ni Buhari ń ṣe, kò ní ifẹ́ ọmọ Nàìjíríà lọ́kàn - Fani-Kayode
O sọ pe "Gẹgẹ bi ọmọ ile Igbimọ Asojusofin, mi o lero pe a nilo biliọnu mẹtadinlogoji fun atunṣe ile naa bayii."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Salam ṣalaye pe kaka ki ijọba na owo yii si Ile Igbimọ Asofin apapọ, iba dara ko fi owo naa ran awọn olokowo kekeke lọwọ.
O ni oun yoo gbe igebsẹ lati tako abadofin naa ni igab ti ile ọhun ba bẹrẹ iṣẹ loṣu kinni ọdun 2020.













