Naira Marley: Adájọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ síwájú di oṣù kejì ọdún 2020

Àkọlé fídíò, Naira Marley: Adọ́jọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ síwájú di oṣù kejì ọdún 20202

Gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fasola, ti gbogbo eeyan mọ si Naira Marley tun yọju sile ẹjọ giga to wa ladugbo Ikoyi nilu Eko lọjọbọ, nitẹsiwaju ẹjọlilu jibiti ti wọn fi kan-an.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro Naira Marley, Olalekan Ojo salaye pe ọlọpa agbefọba ninu ẹri to sọ nile ẹjọ salaye pe oun ko lee sọ boya Marley lu jibiti pẹlu kaadi ti wọn fi n ra ọja.

Ojo ni Adajọ ti sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹtadinlọgbọn ati Ikejidinlọgbọn osu Keji ọdun 2020, to si tun kede pe isunsiwaju ẹjọ naa ko da irẹwẹsi si awọn lọkan laya.