Sex for Grades: Fasiti Kaduna ni ki olùkọ́ lọ rọọ́kún nílé

Oríṣun àwòrán, @kadunauniv
Kete ti iroyin yii jade ni awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga fasiti Kaduna ti kede pe ki olukọ ti wọn fi ẹsun naa kan lọ rọọkun nile.
Omowe Tukur Abdulkadir to jẹ igbakeji aarẹ ẹka to n ṣamojuto ọrọ awọn akẹkọọ ni fasiti Kaduna lo ṣiṣọ loju ọrọ naa.
- Iléeṣẹ́ Instagram wọ́gilé App "Augmented Reality filters" lórí ẹ̀rọ rẹ̀
- Fásitì Ghana lé olùkọ́ méjì tí àṣírí wọ́n tú lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ lọlé
- UNILAG ní kí olùkọ́ míì, Samuel Oladipo to ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ lọ fìdí mọ́lé
- 'Àwọn ti Micra ló jẹ̀bi rògbòdìyàn awakọ̀ tó wáyé lánàá n'Ìbàdàn'
- Ilé aṣọ̀fin Nàìjíríà ń gbèrò ẹ̀wọ̀n f'áwọn olùkọ̀ tó bá dẹnu ìfẹ́ kọ akẹ́kọ̀bìnrin
- Bí àbá yìí bá di òfin tan, ẹ̀yin olùkọ́ tó bá bá àkẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀ rugi oyin
O ni bi ọmọbinrin yii (ti wọn fi orukọ bo laṣiri) ṣe ti rirnirn ijajangbara abo kuro lọwọ awọn olukọ to n halẹ mọ awọn akẹkọọ ni iwadii ti bẹrẹ.
Omobinrin yii fẹsun kan olukọ yii pe o filọkulọ lọ ohun ni eyi ti awọn alaṣẹ fasiti Kaduna dẹ ti ni ko lọ rọọkun nile titi iwadii a fi pari.
Nibi ipade igbimọ alabẹṣekele ti KASU ṣe ni wọn ti ni ki Ogbeni Bala Umar ti ọpọ awọn akẹkọọ n pe ni AB Umar lọ rọọ kun nile.
Omobinrin yii fẹsun kan Umar pe wọn le Umar ni fasiti Ahmadu Bellu (ABU) ni Zaria nitori pe o n fi ilọkulọ lọ awọn akẹkọọbinrin ni eyi to wa ya oun lẹnu pe fasiti Kaduna gbaa siẹẹ.
Ojọgbọn Abdulahi Ashafa to jẹ igbakeji ọga agba ile iwe KASU lo ṣe alaga igbimọ to pe ipadepajawiri naa ni Kaduna.
Abdulahi ni KASU ko ni faaye gba ki olukọ maa dunkooko mọ akẹkọọ rara.
Lẹyin ti fidio BBC jade lori awọn olukọ fasiti Eko ti wọn n huwa buruku yii ni ọmọbinrin naa fi soju opo twitter pe Umar ti huwa buruku yii si oun ri ni fasiti ABU.
Ashafa ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ yii ko ṣẹlẹ ni KASU, o di dandan ki KASU gbe igbesẹ to yẹ ki ọkan awọn obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ le balẹ.
- Ìlé ẹjọ́ ti pàṣẹ pé kí ilé iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá dá ìgbaniwolé dúró
- Jumọkẹ Odetola ṣe ọjọ́ ìbí, Wumi Toriola bímọ, Ṣé ẹ fẹ́ tẹ̀lẹ́ Funkẹ Akindele lọ si Dubai?
- Kò sí àrùn 'Monkey Pox' ní Naìjiria- NCDC
- Ìdí tí a ṣe yọ ọwọ́ Naira Marley kúrò láwo Headies Award ọdún yìí rèé - HipTV
- Seun Egbegbe lo ọdún méjì àti oṣù méje lẹ́wọ̀n láì tìí san béèlì rẹ̀













