Adebutu: Buhari rọ Odole tuntun láti mú kí ìfẹ́ jọba láàrin Yorùbá àti ẹ̀yà míràn

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola
Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ Odole Oodua, Ọlọla Kessington Adebutu lati ri oye isẹnbaye tuntun to jẹ naa gẹgẹ bi anfaani, lati se agbelarugẹ asa ati ise Yoruba.
Aarẹ Buhari, ẹni ti minisita fọrọ abẹle, Rauf Arẹgbẹsọla soju fun, wa se apejuwe ẹya Yoruba gẹgẹ bii ẹya to lagbara pupọ lorilẹede Naijiria, pẹlu afikun pe ki wọn to fi eeyan jẹ oye Odole, o gbọdọ jẹ pe iru ẹni bẹẹ jẹ gbajumọ, to si ti ko ipa ribiribi si isisẹ sin ọmọniyan ati idagbasoke awujọ rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"Inu mi dun pe Oloye Adebutu jẹ oye Odole yii, mo si gbadura pe yoo jẹ oye naa pẹ. O si da mi loju pe o mọ pataki oye yii, nitori awsn akọni ọmọ Naijiria bii Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ati GOK Ajayi ti jẹ oye naa siwaju rẹ."

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola
Buhari ni oun mọ ipa takuntakun ti awọn Odole to siwaju yii ko si idagbasoke orilẹede Naijiria, ti wọn si ri daju pe ajọsepọ to dan mọran wa pẹlu ẹya Yoruba ati awọn ẹya miran, ti Adebutu si gbọdọ se daadaa ju awọn asaaju rẹ yii lọ.
"isẹ nla to wa niwaju Odole ni bi agbelarugẹ yoo se ba bi wọn yoo se maa kọ ede Yoruba lawọn fasiti yika ilẹ wa, mo si tun rọọ gẹgẹ bii ẹlẹyinju aanu lati maa ran awọn mẹkunnu lọwọ, ko si tun jẹ asaaju rere ti yoo maa se atọna alaafia, isọkan, idagbasoke ati ifẹ yika Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ naa, Odole tuntun, Kessington Adebutu ni iran Yoruba ko ni mẹẹri rara ni Naijiria, ti oun yoo si sa ipa lati ri pe asa ati ede Yoruba ko wọọkun rara lasiko toun.








