Italy Parliament: Ìjọba gé aṣòfin àpapọ̀ láti 630 sí 400

Oríṣun àwòrán, EPA
Ile Asofin orilẹede Italy ti di ibo lati ge ida mẹta iye awọn asofin ti yoo ma a soju ẹkun kọọkan lorilẹede naa.
Ile asofin kekere buwọlu ofin to ni ki wọn ge iye awọn asofin lati Ojilelẹgbẹta o din mẹwa si irinwo, ti awọn asofin agba naa yoo si dinku lati okoolelọọdunrun o din marun si igba eniyan.
- Ilé aṣọ̀fin Nàìjíríà ń gbèrò ẹ̀wọ̀n f'áwọn olùkọ̀ tó bá dẹnu ìfẹ́ kọ akẹ́kọ̀bìnrin
- Palmwine Tapping: Ọ̀dọ́mọdé àdẹ́mu ní ìṣẹ́ náà kò wú òun lórí
- Ọmọ Nàìjíríà ti le è sọ̀rọ̀ jù, owó orí gbọdọ̀ gun ìpè lórí fóónù - ìjọba àpapọ̀
- Tọkọtaya ọmọ Nàíjíríà rugi oyin torí wọ́n ń ta ìpara ìbóra lórí ayélujára
- Àtúpalẹ̀ àbá ètó ìsúná ọdún 2020 rèé, wo bó ṣe kàn ọ́ sí
Igbesẹ yii wa lara ileri ibo ti ẹgbẹ oselu Five Star Movement, to je ijọba to wa ni ipo se fun awọn araalu lasiko ipolongo ibo rẹ.
Awọn asofin naa ni adinku to ba iye awọn asofin lorilẹede naa yoo jẹ ki orilẹede Italy ni ọgọọrọ miliọnu Euro nipamọ lati ara owo osu ati owona.
Amọ, awọn alariwisi ọrọ naa ni igbese yii yoo mu ifasẹyin ba isejọba tiwantiwa lorilẹede naa.
Bakan naa ni ofin tuntun naa ko le e wa si imusẹ a fi ti wọn ba se idibo gbogbo-gboo nitori yoo mu ayipada ba ofin orilẹede naa.








