You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Indonesian Youths: Òfin tó de ìbálòpọ ṣáájú ìgbéyàwó kò lè fẹsẹ múlẹ
Gbogbo awọn ọmọ ilẹ Indonesia ni wọn tu jade lọpọ yanturu lati fẹhonu han tako ofin ibalopọ ni ilẹ naa.
Awọn ara ilu naa ni ki alaṣẹ ilẹ naa maṣe mu erongba wọn ṣẹ pe ko maṣe si ibalopọ ṣaaju igbeyawo.
Nibi ifẹhonu han yii ni awọn Ọlọpaa ti yin tajutaju si wọn ti onikaluku si tuka ni iwaju ile Igbimọ Aṣofin ilẹ naa.
Ifẹhonu han yii tun ṣẹlẹ ni ọpọlọpọ awọn ilu miran yika orilẹ ede ọhun.
Abadofin naa ni yoo dẹkun oyun ṣiṣẹ ati ibara ẹni lopọ laini ikora ẹni ni ijanu.
Kíni ofin abadofin yii tumọ si ni Indonesia?
Lara awón ohun ti o wa ninu abadofin naa ni wi pe;
Ẹwọn ọdun kan pere ni ibaṣepọ ṣaaju igbeyawo
Gbigbe papọ akọ ati abo lai ti i ṣe igbeyawo yoo gbe ẹwọn oṣu mẹfa pọn.
Sisọ ọrọ alufanṣa si Aarẹ, Igbakeji Aarẹ, ẹsin, ile iṣẹ ijọba ati titapa si asia ati orin orilẹ-ede yoo di ẹṣẹ.
Oyun ṣiṣẹ yoo ni ijiya ẹwọn ọdun mẹrin lori lai ki n ṣe pe o ni i ṣe pẹlu ilera obinrin naa.
Abadofin yii ni o yẹ ko wọ ile aṣẹ lọ ni ọjọ Iṣẹgun sugbọn ti Aare ilẹ naa, Joko Widodo sun un si ọjọbọ ọsẹ yii.
Kini o wa fa ifẹhonuhan?
Idi ifẹhonuhan naa waye ni awọn olu ilu kaakiri Indonesia bẹrẹ lati Jakarta, Yogyakarta ati Makassar ni erekuṣu Sulawesi ni eyi ti ẹru n ba awọn eniyan pe o ṣeeṣe ki ijọba sọ abadofin naa di ofin.
Awọn eniyan woye pe yoo pakun eto ọrọ aje ilẹ naa to da gẹgẹ.
Wọn tun n binu lori ọna gbigba ofin tuntun wọle laiṣe lodi si iwa jẹgudu jẹra.
Pupọ lara awọn ti o jẹ olufẹhonuhan naa ni akẹkọọ ti wọn jade lọpọ yanturu si gbogbo ilu orilẹ-ede naa.
Gbagede ibi ifẹhonu han ni Olu Ilu ilẹ naa, Jakarta nibi ti wọn ti n bere lati ri Olori awọn Aṣofin, Bambang Soesatyo.
Awọn olufẹhonu han yii ni wọn n ju okuta si awọn Ọlọpaa ti Ọlọpaa naa n yin tajutaju si wọn.
Ọkan lara patako ifehonu han kan ti obinrin kan gbe dani sọ pe, ẹya ara mi kii ṣe ti Ijọba.
Ko din ni ẹgbẹrun marun un awọn Ọlọpaa ti wọn wa ni bi ifẹhonu han naa.