Baby Factory: Orí kó aboyún mọ́kàndínlógun yọ lọ́wọ́ àwọn akóni ṣòwò ẹrú

Ọwọ palaba awọn akoni ṣowo ẹru kan ti ṣegi nigba tawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko mu awọn afunrasi meji ati awọn alaboyun mọkandilogun kan nilu Eku.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko DSP Bala Elkana fi sita, o ni ọwọ awọn agbofinro tẹ awọn aṣebi yi ni ile kan to wa ni adugbo Ikọtun nilu Eko.

Nibẹ ni wọn ti ri awọn alaboyun ti ọjọ ori wọn ko ju bi ọdun mẹẹdogun si mẹjidinlọgbọn lọ.

Koda o ni awọn tun ribi doola ẹmi awọn ọmọde mẹrin.

Gẹgẹ bi ohun ti o ṣalaye ninu atẹjade naa, wọn gbe awọn aboyun naa wa lati ipinlẹ Rivers, Cross River, Akwa Ibom, Anambra, Abia ati Imo.

Ẹni to jẹ iya isalẹ awọn to n ko ni ṣowo ẹru naa,arabinrin Oluchi lati ilu Mbano nipinlẹ Imo la gbọ pe o ti na papa bora.

Eredi kiko awọn oluyun yi si ibi ti wọn wa ni pe wọn yoo ta awọn ọmọ ti wọn ba bi ni iye owo ọkẹ mẹẹdogun si ọkẹ marundinlọgbọn.

Komisana ọlọpaa nipinlẹ Eko Zubairu Muazu ti ni ki wọn ti ile ti wọn ti ri awọn aboyun yi pa.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn ajọ miran n jijọ n pawọpọ lati mu awọn to n ṣagbatẹru owo buruku yi.