Samson Siasia: Orí ti kó ìyá Siasia yọ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé lẹ́yìn oṣù méjì ààbọ̀

Lẹyin bi oṣu meji ati aabọ, awọn ajinigbe ti fi iya akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Samson Siasia silẹ.

Ewerikumo Siasia to jẹ ẹbi Siasia lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC wi pe iya agbabọọlu Naijiria nigba kan ri, Beauty Siasia kuro lakata awọn ajinigbe lalẹ ọjọ Abamẹta.

Bakan naa lo sọ fun BBC pe pe awọn ajinigbe ọun tun da awọn obinrin meji miiran silẹ yatọ si mọmọ Siasia.

Lọjọ kẹẹdogun oṣu keje ọdun 2019 lawọn ajinigbe gbe iya Siasia niluu Odoni to wa nijọba ibilẹ Sagbama nipinlẹ Bayelsa.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bayelsa, Butswat Asimin naa tun fidi rẹ mu lẹ pe iya Siasia ti gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.