Italy da ọ̀pọ̀ Aláboyún àt'àwọn arìnrìnàjò obinrin padà níbodè

Nàìjírìà ní orílẹ̀-èdè kẹ̀ta tó pòjù lọ tó ń kọjá lọ sórílẹ̀-èdè Libya lọna àìtọ́ lẹ́yìn Syria àti Afgan.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ní ìjọba ti dá pádà wále láìpẹ́ yíì nítorí iṣekú-pani to ń waye níbẹ̀ láti ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè Libya.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ènìyàn yìí máa ń rápálá wọ Libya lójúnà àti kọja lọ sí orílẹ̀-èdè Italy.

Ní báyìí èsúrú ọ̀rọ̀ náà ti pàdídà, ó ń lé ajá, bí òrílẹ̀-èdè Italy ṣe fárígá pé àwọn àrinrìnàjò lọ́nà àìtọ́ tí àjọ ẹléyin jú àànú orílẹ̀-èdè Germany kan tí wọn ń pè ni SOS Méditerranée dóòlà kò ni wọlé sí Italy.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ènìyàn mọkàndinlọgbọnlélẹgbẹta ní àwọn àjọ náà dóòlà nínú odò Meditereanian lágbàgbè tó súnmọ́ Libya.

Kini ìdí ti Italy fi Fariga:

Mínísítà Italy fún ọ̀rọ̀ abẹ́lé, Matteo Salvini, ni orílẹ̀-èdè Italy sọ pe, apá ibi tí wọ́n ti kó àwọn arinrìnàjò ọ̀hún súnmọ́ orílẹ̀-èdè Malta ju Italy lọ.

Yàtọ̀ sí èyí, Italy ti pinnu pe òhún yóò fi òpin sí ìrìnàjò lọ́nà àìtọ́ wọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ti sọ ọ̀nà ibẹ̀ di ibi tí wọn ń gbà wọ Yuroopu.