You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Tunde Bakare: Irọ́ ni, mi ò sọ pé mọ fẹ di Ààrẹ ní 2023
Pasitọ ati Olori Ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ti ni irọ patapata ni iroyin ẹlẹjẹ wi pe oun lo ma a gba ipo aarẹ ni ọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari.
Bakare sọ eyi lasiko to n ba awọn ara ijọ rẹ ni agbeegbe Ọgba ni ipinlẹ Eko, sọrọ ni Ọjọ Isinmi.
O sọ wi pe fidio ti oun fi sita lati bi ọdun diẹ sẹyin ni awọn eniyan miran ṣẹṣẹ n gbe jade lati fi ba oun lorukọ jẹ.
O ni Olorun fi osumare han oun nipa Naijiria, eleyii to fi han wi pe ayipada yoo deba orilẹ-ede Naijiria.
Bakan naa lo ni Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo yoo bori awọn ẹni ibi to n sọrọ kobakungbe nipa rẹ, ati pe awon ọta Oṣinajo yoo pofo.
- Ọpẹ́ o! Ìyá Siasia kúrò lákàtà àwọn ajínigbé lẹ́yìn oṣù méjì ààbọ̀
- 'Èmi àti Toyin Abraham ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ọdún méjì torí ìjà òun àti Lizzy'
- Ẹ yéé purọ́ kiri! Ìdí rèé tí Aisha Buhari kò tíì padà sí Nàìjíríà- Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Ọgbọ́n àrékérekè ní ìjọba ń dá lórí àfikún owó oṣù òṣìṣẹ́, a o sí ní gbà- NLC
Pasito Tunde Bakare fikun un wi pe Osinbajo ni yoo rẹrin igbẹyin lori awọn ọta rẹ, nitori naa ki o lọ sinmi pẹlu ifọkanbalẹ.