Action Against Hunger: Ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí ISWAP ṣekú pa àláànú kan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State in West Africa, ISWAP ti pa ọkan lara awọn oṣiṣẹ ẹlẹyinju aanu mẹfa ajọ Action Against Hunger ti wọn mu loṣu Keje ọdun yi.

Ninu atẹjade ti ajọ naa fi sita, wọn fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ti wọn si ni awọn ko mọ eleyi ti o jẹ ninu awọn to wa ni ahamọ.

Saaju ni ọjọru ni akọroyin Ahmed Salkida ti kọkọ tu kẹkẹ ọrọ yi sita loju opo Twitter

Salkida ṣalaye ninu ọrọ rẹ pe ISWAP lawọn pa oṣiṣẹ naa to jẹ ọkunrin nitori pe ijọba n mu awọn ṣere ni lẹyin ọpọ oṣu ti awọn ti jọ n ṣe idunadura.

Awọn alaṣẹ Naijiria to fi mọ awọn ologun ko ti i ṣọrọ lori iṣẹlẹ yi.

Salkidatun sọ pe awọn agbesunmọmi naa ninu fọnran fidio ti oun ri ṣeleri lati pa awọn oṣiṣẹ to ku.

Iṣẹlẹ yi waye lẹyin igba diẹ ti ileeṣẹ ologun Naijiria ti ileeṣẹ Action Against Hunger pa ni Maiduguri.

Wọn fẹsun kan wọn pe wọn lẹdi apo pọ pẹlu ikọ Boko Haram.

Ẹwẹ, ajọ ẹlẹyinju aanu miran, Mercy Corps kede lọjọru pe awọn alaṣẹ Naijria ti sọ agadagodo si ileeṣẹ awọn to wa ni Maiduguri ti wọn si ni kawọn dawọ iṣẹ duro lagbegbe naa.