Prince Harry, Meghan àti ọmọ wọ̀n, Archie n ṣe àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ mẹ́wàá silẹ̀ Áfríkà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọlọla ọmọọba ilẹ Gẹẹsi Prince Harry ti a tun mọ si Duke ti Sussex, iyawo rẹ Megan ati ọmọ wọn, Archie ti bẹrẹ abẹwo ọlọjọ mẹwaa silẹ Afrika.

Orile-ede South Africa ni wọn kọkọ balẹ biba si ti a si gbọ pe irinajo ọlọjọ mẹwaa naa bẹrẹ ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan titi di ọjọ keji, oṣu Kẹwaa.

Meghan ati Archie yoo lo ọjọ mẹwaa ni South Africa nigba ti iroyin sọ pe Prince Harry yoo tẹsiwaju ni tiẹ lọ si Angola, Malawi ati Botswana lọjọ Ẹti.

Lẹyin igba naa ni Prince Harry yoo pada wa si South Africa wa ba awọn mọlẹbi rẹ ti wọn yoo si jijọ pada si London.

Kini idi ti Omọ ọba ṣe wa?

Prince Harry n lọ si Angola lati kan sara si iṣẹ ti iya rẹ to di oloogbe Princess Diana of Wales ṣe nibẹ.

Nigba aye rẹ, o jẹ aṣaaju nibi ipolongo to waye lọdun 1997 lati fi ofin de lilo ado oloro ti wọn maa n ri mọ ilẹ (land mines).

A tun gbọ pe yoo kẹdun lori iku ọmọ ologun kan ti o padanu ẹmi rẹ ninu ọgba nla ti wọn ko awọn ẹranko si.

Lọgbọn ọjọ, oṣu Kẹsan an ni Prince Harry yoo mẹnuba ipenija ẹdinku to n ba iye ẹranko to wa ninu igbo.

Loju opo Twitter Harry ati Iyawo rẹ, wọn fi ikede sibẹ pe Ọmọọba Harry yoo tẹsiwaju pẹlu iṣẹ rere ti iya rẹ ṣe ni Angola.

Ni tirẹ, Duchess Megan yoo ṣabẹwo sawọn agbegbe kan eleyi ti yoo ṣafihan mimu idagbasoke ba awọn eeyan lẹsẹpupu.

Yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹgbẹ aladani lati mu agbega ba ọrọ eto ẹkọ awọn obinrin to fi mọ igbe aye alaafia ati ilera to peye fun wọn.

Bakan naa ni Megan yoo ṣe ipade pẹlu awọn olokoowo kan nilẹ South Africa ki wọn to pari abẹwo wọn.