You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
El-Rufai: Àwọn aráàlú ń sọ̀rọ̀ lórí ọmọ gómìnà El-Rufai tó wọ iléèwé ìjọba ní Kaduna
Lootọ asiko ti awọn ọmọ n lọ ileewe pada niyi lẹyin isinmi ọlọjọ gbọọrọ. Oniruuru ariwo si lo n waye lori iwọle naa paapaa lori sisan owo ileewe laarin awọn obi.
Amọṣa, ọmọ gomina ipinlẹ Kaduna, ElRufai naa lọ sileewe loni o ariwo si ta. O daju pe ko si bi ariwo owo ileewe sisan ṣe lee dide nitori baba rẹ, gẹgẹ bii gomina ri jajẹ yatọ si pako lawujọ.
Ariwo to ta ni pe ileewe ijọba ni ọmọ gomina Elrufai naa ti lọ forukọ silẹ bayii.
O daa, ẹ wo bo ṣe ri.
Nigba ti baba rẹ, gomina Elrufai n polongo fun idibo rẹ si ipo gomina fun saa keji lo ti fi ẹnu ja ewebẹ sawo fawọn araalu pe bi wọn lee dibo fun oun ti oun wọle, ileewe ijọba ti awọn ọmọ tiwọn n lọ ni ọmọ ti oun naa yoo lọ.
Ileri ti gomina Elrufai ṣe ni ọdun naa lọun lo wa muṣẹ bayii nitori, odidẹrẹ awo olokun, boo ba johun gbe, maa johun gbe.
Nibayii, Abubakar Al-Siddique El-Rufai ọmọ gomina El-Rufai ti di akẹkọ nileewe alakọbẹrẹ Kaduna Capital School. Baba rẹ gan an lo si faa lọwọ lọ fi orukọ silẹ nibẹ.
O daa o, ki wa ni awsn eeyan n sọ lori eyi?
Lati igba ti gomina El-Rufai ti kede rẹ naa ni olukuluku ti n wi tẹnu rẹ lori rẹ. Bi awọn kan ṣe n kan saara sii naa ni awọn kan n kan an ni ikuuku.
Fun apẹrẹ, J.J. Omojuwa kan sara si gomina El-Rufai lori oju opo Twitter rẹ 'lootọ awọn kan sọ pe o tun ileewe naa ṣe ki o to fi ọmọ rẹ si. Bi o ṣe yẹ ko ri naa niyi nitori ti awọn to dipo ilu mu ba n titori ọmọ wọn mojuto awọn ileewe ijọba, gbogbo wa la o jijọ pọn la nibẹ."
Ni tirẹ, @tissann_ ni, " O dabi ẹni pe awọn ti ko gbe ninu ipinlẹ Kaduna lo n wo gomina El-Rufai gẹgẹ biiohun gidi kan fun ipinlẹ naa."
bakan naa ni@I_Am_Ilemona koro oju si gomina El-Rufai. o ni pe o na igba miliọnu naira si ileewe ko to ṣee lọ fun ọm rẹ finhan iru ipo ti ileewe naa wa.
Ẹ gbọ naa, ki ni ero tiyin. Ẹ lọ soju opo facebook wa ni @bbcnews Yoruba tabi oju opo @bbcnewsyoruba lori instagram ki ẹ fi ero sibẹ. Ire o.