RevolutionNow: Falana àtàwọn míì ṣe àpérò l'Eko lẹ́yìn tí DSS kọ́kọ́ ti gbọ̀ngàn tí wọ́n fẹ́ lò pa

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, ọlọpaa atawọn ologun kọkọ ti ibi ti awọn ajijangbara kan ti fẹ ṣe apero lori ifẹhonu han #RevolutionNow ni Lagos Centre ni Ikeja lọjọ Aje.

Ṣugbọn agbẹjọro Femi Falana jade bi awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti sọ fawọn akọroyin pe ki wọn ba eṣẹ wọn sọrọ.

Bakan naa lo bawọn eeyan sọrọ ko to wọ gbọngan ipade ọhun lọ.

Laisi ani ani, ipade naa pada waye ni Ikeja, niluu Eko lọjọ Aje.

Àjọ DSS ti gbọ̀ngàn ìpàdé #RevolutionNow pa ní Ikeja

Awọn ilumọọka ajijagbara bi Ọjọgbọn Wole Ṣoyinka, agbẹjọro Femi Falana atawọn mii la gbọ pe wọn fẹ pade ni Lagos Centre fun apero naa tẹlẹ.

Ṣugbọn akoroyin BBC, Andrew Gift to ṣabẹwo si gbọngan naa sọ pe wamuwamu lawọn oṣiṣẹ DSS, ọlọpaa atawọn ologun duro siwaju bẹ ti wọn ko si jẹ ki ẹni kankan wọ bẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe wọn fẹ ṣapero lori ohun ti wọn pe ni iwa tani yoo mu mi ti ijọba gunle lori bi wọn ṣe ti Omoyele Ṣowore to ṣagbatẹru iwọde Revolution Now atawọn ajijagbara mii mọ le.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ajọ to n ṣagbatẹru ifẹhonu han lati ja fun ẹtọ awọn ọmọ Naijiria, CORE lo fẹ pade ni Lagos Centre fun apero naa.

Yatọ si Ọjọgbọn Ṣoyinka ati agbẹjọro Falana, awọn eekan mi to tun wa lara ẹgbẹ naa ni Ọjọgbọn Omotoye Olorode, Ọgbẹni Femi Aboriṣade, Ọjọgbọn Anthony Kila, agbẹjọro Affiong L. Affiong ati bẹẹ bẹẹ lọ.