You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọ̀dọ́ ẹ̀yà Hausa kan àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 'Awawa boys' da ìgboro Eko rú
Wahala nla kan ti bẹ silẹ laarin awọn ọdọ kan lagbegbe Oke Odo ni ipinlẹ Eko.
- Ẹ yìnbọn pa ọ̀daràn tí ẹ bá rí níbi kíbi, Buhari pàṣẹ fáwọn ológun
- Ike Ekweremadu, igbákejì ààrẹ ilé aṣòfin àgbà tẹ́lẹ́ rí èèmọ̀ he nilùú Germany!
- Ayédèrú Ọ̀ṣun ni wọ́n ń bọ lónìí, kìí ṣe ojúlówó - Bàbá Ọlọ́ṣun tún figbe ta
- Wá gbàkàrà, gba dùǹdù ni Tottenham fi gba ọ̀mì lọ́wọ́ Manchester city
- Fayemi fojú Alufa to fipa bá ọmọde lòpọ̀ síta l'Ekiti
- El-Zakzaky: Arúfin ni ijọba Muhammadu Buhari gan-an - Ladoja
Ohun ti awọn iroyin kan n sọ ni pe awọ̀n ọdọ ẹya Yoruba ati awọn akẹgbẹ wọn lati ẹya Hausa ni wọn fija pẹẹta lọjọ aiku bi o tilẹ jẹ wi pe ko tii si ẹni ti o lee sọ ohun ti o ṣokunfa rogbodiyan naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni ọja Oke odo ni ija naa ti waye, bẹẹni ọpọ dukia lo parẹ sinu iṣẹlẹ naa ti ọpọ eeyan si fara pa pẹlu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni wahala naa waye laaring awọn ọmọ Hausa kan ti wọn maa n ṣa ilẹ kaakiri atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti orukọ wọn n jẹ Awawa boys.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana to ba ikọ BBC news sọrọ ṣalaye pe wọn ti da ikọ ọlọpaa kogberegbe kan si agbegbe naa ti wọn si ti pana wahala ọhun.