You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Big Brother Naija: O tó gẹ́; a kò fẹ́ ìwòkuwò mọ́ ní Nàijíríà
Ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria ti fi aidunnu rẹ han si ibalopọ ti o n waye lori eto Big Brother Naija (BBN), ti o n lọ lọwọ.
Otunba Segun Runsewe, Alakoso agba fun ile iṣẹ to n ri si ọrọ aṣa ati iṣe lorilẹ-ede Naijiria, National Council for Arts and Culture (NCAC), lo fi ọrọ yi lede.
O fi ero ijọba han nigba ti o gbalejo ààrẹ ẹgbẹ àwọn obinrin National Council of Women Society, Gloria Shoda, lọjọ Ẹti.
Ọtunba Roṣẹwẹ sọ pe oun ti fi ọrọ naa lọ ajọ to n mojuto igbohun safẹfẹ lorilẹ-ede yi, iyẹn NBC.
Bakan naa lo ṣalaye pe: "Mo maa mu ọrọ Big Brother Naija lọkunkundun".
O ni: Mo ti ba awọn ajọ to n risi igbohun safẹfẹ lorilẹ-ede yi sọrọ, nitori pe ohun to n sẹlẹ lori BBNaija jẹ nkan ti o buru jai.
Biba ara eni ni ibalopọ lori afẹfẹ kii ṣe aṣa ilẹ wa rara."
Gloria Shoda nitirẹ wi pe oun ko lodi si eto BBNaija, sugbọn biba ara ẹni lopọ lori afẹfẹ je ohun ti ko dara rara.
O tẹ siwaju wi pe, "iwa ibaraẹni lopọ lori afẹfẹ je ohun ti emi ko faramọ rara, o si tun jẹ nkan ti o leè ni ipa buburu lara awon ojẹ wẹwẹ to n bọ leyin."
Runsewe ni ijọba Naijiria yoo ṣagbekalẹ eto miran ti yooo maa fọn rere aṣa ati iṣe wa fun iran to m bọ yatọ si ti BB Naija to n ṣafihan ibalopọ.
Akitiyan ileeṣe BBC lati ba aṣoju ile iṣẹ ti n ṣe amojuto ọrọ aṣa ati iṣe ni Naijiria ati ajọ BBNaija sọrọ lori koko ọhun bayii lo ja si pabo.