Adeleke Vs Oyetola: Òní ni ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ yóò kéde ìdájọ́ lórí èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun

Ọjọ a da ti pe.

Loni ni ile ẹjọ to ga ju lọ lorileede Naiijiria yoo kede idajọ lori esi idibo Gomina ipinlẹ Osun.

Gomina Gboyega Oyetọla ati Sẹnẹtọ Ademola Adeleke ni wọn jijọ n ṣẹjọ lori ọrọ yii. Ṣaaju ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti sọ pe Oyetola lo jawe olubori ninu idibo naa.

Amọ ṣa oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnẹtọ Ademola Adeleke ta ko idajọ yIi to si gba ile ẹjọ giga lọ.

Bi nnkan ba ti ṣe n lọ si ni BBC Yoruba yoo ma fi too yin leti.

Ọlọ́pàá ní àwọn ti gbáradì fún ìdájọ́ ilé ẹjọ́ agba pátápátá

Ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Osun naa ti ni awọn ti wa nikalẹ, lati pese aabo fun awọn ara ilu ibikibi to wu ki idajọ ile ẹjọ to ga ju lọ ni Naijiria, lori esi idibo gomina ipinlẹ Osun to waye ni ọdun to kọja ba fi si ni ọjọ Ẹti.

Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ naa, Folashade Odoro sọ fun awọn akọroyin ni ipinlẹ naa wi pe awọn ti wa ni digbi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹjọ naa lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin ti oludije ẹgbẹ oṣelu APC Gboyega Oyetola bori oludije PDP, Ademola Adeleke, nigba ti wọn kọkọ gbe ẹjọ naa lọ iwaju ile ẹjọ kotẹmilọrun ni oṣu karun un.

Ti ẹ ba ranti, ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ esi idibo kọkọ dajọ ni oṣu Kẹta ọdun yii wi pe, Adeleke lo jawe olubori ṣugbọn Oyetola gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lori ọrọ naa.

Ṣugbọn ile ẹjọ kotẹmilọrun yii ẹjọ naa danu, ki Adeleke to gbori le ile ẹjọ agba patapata ni Naijiria.

Ọjọbọ ni Adeleke yoo mọ ibi ti ọrọ yoo fi si, ti awọn ara Ipinlẹ Osun yoo si mọ ẹni ti yoo jẹ ojulowo gomina wọn.