HIV Patients: N kò ní ìbálòpọ̀ rí kí ń tó ní HIV

Brian Omondi, ti wọn bi pẹlu aarun HIV, bẹrẹ si ni lo akanṣe oogun fun aarun naa, anti-retroviral (ARV) nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹwaa.

Amọ ṣa, igba to pe ọmọ ọdun mẹrinla, lẹyin ti iya rẹ ti ku, lo to o mọ aisan ti awọn oogun naa wa fun.

O ti pe ẹni ọdun mejilelogun bayii, o si n ṣiṣẹ ipolongo igbogun ti aarun HIV pẹlu ṣọọṣi kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Kii ṣe igba ti wọn bi mi ni mo ko aarun naa. Mo kan ranti pe nigba ti mo wa l'ọmọde, mo maa n ṣaiṣan nigbogbo igba, iya mi si mu mi lọ sile iwosan fun ayẹwo.''

''Igba ti wọn ṣe ayẹwo fun mi ni wọn ri i pe aarun HIV ni mo ni. Mo bẹrẹ si ni lo oogun, ṣugbọn iya mi ko fi igba kankan sọ idi ti mo fi n lo awọn oogun naa fun mi.''

Igba to lọ gbe lọdọ ibatan rẹ kan lẹyin ti iya rẹ ku, ni awọn aladugbo mọ pe o ni HIV, awọn ẹlẹgbẹ rẹ si bẹrẹ si ni i fi ṣe ẹlẹya.

Awọn obi maa n kilọ fun awọn ọmọ wọn lati ma ba a awọn to ni aarun HIV ṣere.

Botilẹjẹ wi pe awọn ọdọmọde ati ọdọ lo pọ ju lara awọn to n gbe pẹlu HIV ni Kenya, ati ilẹ olooru Afrika, ọpọ ninu awọn ti wọn bi pẹlu aarun naa lo n gbe igbeaye wọn laijẹ ki ẹnikẹni o mọ.

Awọn obi kan l'orilẹede Kenya maa n pa aṣiri aarun HIV wọn mọ titi wọ saare, ti wọn si maa n fi awọn ọmọ wọn sinu okunkun ati ailera.

Ọgbẹni Omondi sọ pe, oun ko da iya oun l'ẹbi pe ko sọ ootọ fun oun.

'Mo ro pe o yẹ ko sọ fun mi, amọ mi o tun le da a l'ẹbi nitori pe o n gbiyanju lati daabo bo mi gẹgẹ bi ọmọde.''

Amọ, o ni o di igba ti awọn eniyan ba to o yi ihuwasi wọn pada si awọn ti wọn bi pẹlu HIV, ki awọn alarun naa to ma a gbe igbe aye ominira, tabi ni ọrẹ ati ololufẹ lai si ibẹru ati idiwọ.

Bakan naa ni ọrọ ri fun Winnie Orende, to ti pe ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn bayii. Iyalẹnu ati ibanujẹ nla lo jẹ fun nigba to mọ pe oun ni aarun HIV nigba to pe ọmọ ọdun mejila.

'Nigba ti iya mi ku, lẹyin oṣu meji, dokita ni ẹgbọn mi obinrin, o si pe mi ki n da wa si ileewosan lati ri oun.''

Dokita naa mọ pe, aarun naa lo pa iya rẹ - o si fẹ ẹ ṣe ayẹwo fun lati mọ boya oun naa ni. Esi ayẹwo fihan pe, o ni aarun naa.

Ohun to buru ju ni pe, Winnie to kere julọ ninu awọn ọmọ iya rẹ, lo ni aarun naa lati ara iya wọn.

'Pẹlu ọjọ ori mi, iporuru ọkan ba mi. Mi o ni ibalopọ ri; mi o ki n ṣe aṣẹwo, bawo ni mo ṣe wa ni aarun HIV?

Ko kọkọ gba esi ayẹwo naa gbọ, afi igba to bẹrẹ aisan, ti wọn si gbe e lọ sile iwosan ni aimọye igba.