Osun Election Tribunal: Èyí ni òkodoro ìdájọ tí àwọn eniyan ìpínlẹ̀ Ọsun ti ń reti- Oyetola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun Gboyega Oyetola ti sapejuwe ìdájọ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọrun gẹ́gẹ́ bii èyí ti àwọn ènìyàn Ọsun ti n reti tipẹ.

Gómìnà sọ èyí di mímọ lónìí ọjọ́bọ̀ lásìkò to n ba awọn alatilẹyin sọrọ nibi ti wọn ti ń dáwọ̀ọ́ ìdùnù lóri abájade ìdájọ ilé ẹjọ kòtẹ́milọ́rùn to wáyé nílùú Abuja.

Loni ní adájọ ile ẹjọ kòtẹmilọrun lẹ́yìn àyẹwò fínífíní lórí ìdájọ tó sááju wáye nile ẹjọ tó ń gbejọ ìdìbò ni ìpínlẹ̀ Osun to ni Sẹnitọ Ademola Adeleke ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) ló jáwe olúbori kéde pe Gboyega Oyetola ló jáwe olúbori.

Ní bi tí wọn ti n dáwọ̀ọ̀ ìdùnù ni ìlú Oṣogbo Oyètọla ni òun kò le fi ìdìnú òun pámọ lóri idajọ to wáye náà, ó ni kò lè jẹ ìfòyà fún òun ti oludikje lábẹ òṣèlú PDP ba morile ile ẹjọ to ga jùlọ.

O ni lái ṣe pe ènikẹni ké si gbogbo àwọn ará ìpínlẹ Ọṣun, gbogbo wọn ló tu síta láti ṣe ajọyọ aṣeyori náà.

Osun Elections: Gboyega Oyetola borí Adeleke n'ílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Ile ẹjọ kotẹmilọrun to gbọ ẹjọ nipa fa ki fa a to waye lasiko idibo gomina ipinlẹ̀ Ọṣun ninu oṣu kẹsan ọdun 2018 ti kede Gboyega Oyetola gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.

Lana, ile ẹjọ kotẹmilọrun to n gbejọ lori ọrọ ẹni tó lẹtọ lati jẹ Gomina nipinlẹ Osun laarin Gboyega Isiaka Oyetola ati Ademola Adeleke fi ikede pe awọn yoo dajọ naa lọjọbọ.

Eto Idajọ ti wọn fi ikede rẹ sita ninu iwe ile ẹjọ naa ni awọn alatilẹyin awọn ti ọrọ naa kan fi sọwọ sawọn oniroyin yoo waye laago mẹsan owurọ nile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja.

Ni kete ti idajọ naa hande ni awọn ọtọkulu ti n fi sita lori ẹrọ ayelujara.