George Weah tí padà sí ọ́fíìsì rẹ̀ tó fí sílẹ nítorí ejò

George Weah

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Mọjamọsa la fi mọ akinkaju ọkunrin.

Lẹyin to fi ọfisi rẹ silẹ tori awọn ejo meji,Aarẹ orileede Liberia George Weah George Weah ti pada sibẹ lati ma ba iṣẹ lọ.

Weah to fi igba kan jẹ iluọmọọka agbabọọlu pada si ọfisi rẹ lẹyin ọsẹ meji ti o fi ibẹ silẹ fun awọn ejo naa.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka,wọn fin oogun kẹmika to lagabara si ọfisi rẹ daada ki wọn to ni pe ko pada sibẹ l'Ọjọru

Koda a gbọ pe o gab alejo lọjọ to ko wọ ofisi rẹpada ti ṣe ọjọru.

Igbakeji aarẹ tẹlẹ Joseph Boakai ti o fidirẹmi lọwọ Weah ninu idibo aarẹ 2017 lo ba lalejo.

Lati ọdun 2006 ti ina ti jo ile aarẹ ni wọn ti gbe ọfisi aarẹ lọ si ọfisi alaja mẹfa ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okere n lo.

Awọn ejo to le aarẹ kuro lọfisi la gbọ pe wọn jade lati inu ilẹ ti wọn si sa wle pada nigba ti awọn eeyanfẹ pa wọn.