Ìgbàjọba Seyi Makinde: Hosea Agboọla, Bisi Ilaka wà lára ọmọ ìgbìmọ̀

Seyi makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde

Gbogbo eto lo ti de bayii fun igbesẹ igbejọbakalẹ lati ọwọ Gomina to wa lori oye Abiọla Ajimọbi si eleyi ti araluu dibo yan nipinlẹ Oyo, Seyi Makinde.

Lọjọ Aje, ọjọ Kinni, oṣu Kẹrin ọdun 2019 ni wọn ṣe ifillọlẹ awọn ọmọ igbimọ ẹlẹni mẹwaa kan ti yoo ri si eto igbejọbakalẹ naa.

Lara awọn eeyan ti yoo lewaju igbimọ naa la ti ri igbakeji akojanu tẹlẹ fun ile asofin agba nilẹ wa, Senetọ̀ Hosea Ayọọla Agboọla ati oludije tẹlẹ fun ile asofin agba lẹkun idibo Oyo North, Oloye Oyebisi Ilaka.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọmọ igbimọ yoku ni Wale Adepọju, Debọ Ogundoyin, Oyedijọ Bọsẹde Ayọ Famọla, Ọlọlade Ajibọla, B.V Bello, Adeniyi Babatunde ati Seun Ashamu.

Àkọlé fídíò, Ayekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Bakan naa ni ẹgbẹ oselu PDP yoo tun se ifilọlẹ awọn igbimọ tẹẹkoto bii ogun mii fun eto igbajọba to n bọ lọna naa.