Nigeria vs Seychelles: Ikọ Super Eagles bori Seychelles pẹ̀lú 3-1 nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ AFCON

Super eagles

Oríṣun àwòrán, @thenff

Àkọlé àwòrán, Orilẹ̀ede Nigeria ati Seychelles yoo waako ni agogo mẹrin ọjọ ẹti

Orilẹede Naijiria jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn Seycheles loni ọjọ Ẹti ninu idije ife ẹyẹ AFCON ti ọdun 2019.

Nigba ti ere bọọlu naa maa pari, ikọ Super Eagles ti gba ẹjẹ lẹnu Seychelles pẹlu ami ayo mẹta si ọkan.

Odion Ighalo, Henry Onyekuru ati Moses Simon lo gba ayo mẹtẹẹta wọle.

Naijiria bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu agbara bi Alex Iwobi ṣe jẹ tẹtẹ ayo kan ni iṣẹju karun-un, ṣugbọn Ahmed Musa to yẹ ko ran an lọwọ ko jẹ ki ayo naa wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi o tilẹ jẹ pe abajade ifẹsẹwọnsẹ naa ko lee ni ipa lara ilepa eyikeyi ikọ mejeeji ninu bi nnkan ṣe ri ṣaaju ninu idije naa, ireti wa pe awọn ikọ mejeeji yoo ta biọbiọ lati ṣe bi ọkunrin.

Ni bayii, olukọni ikọ Super eagles ti gbe orukọ awọn agbabọọlu ti yoo ṣoju orilẹede Naijiria jade bayii.

Orukọ wọn ree, Uzoho ni aṣọle akọkọ, Shehu, Emeruo, Ekong, jamilu, Ndidi, Etebo, Musa, Onyekuru, Iwobi ati Ighalo ni yoo bẹrẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Bakan naa, Onuachu, Balogun, Ogu, Simon, Ezenwa, Awaziem ati ajayi naa yoo wa ni ikalẹ.