You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fake News: BBC kọ́ lọ́ ṣe ètò ìrànwọ́ ìwé kíkà
Ìròyìn òfegè ni ìròyìn tó ń lọ pé iléeṣẹ́ BBC ń ṣe ètò ìrànwọ́ ìwé kíkà lóríi www.giveaway-bbc.com.
Àwọn èèyàn ti ń lọ sí orí òpó ayélujára ọ̀hún àti òpó Facebook rẹ̀, https://www.facebook.com/GiveawayBBC/ tipẹ́.
Ṣùgbọ́n ilé iṣẹ́ BBC kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú òpó náà.
Eléyìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìròyìn òfegè tí àwọn èèyàn ń gbé ka lóde òní.
A rọ àwọn èèyàn kí wọ́n mọ̀ dájú pe ilé iṣẹ́ BBC kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú òpó náà.
Nigba kigba ti BBC ba fẹ ṣe eto ni a maa n gbee soju opo wa ni bbcnewsyoruba lori facebook ati instagram pelu lori www.bbc.com/yoruba lori ikanni website wa.