Tọkọ-tayà kọ ara wọn silẹ nitori Buhari nínú ìdìbò 2019 tó m bọ̀

Abdullahi ṣalaye fun BBC pé oun ti kọ iyawo oun silẹ lataari pe ó fe ki Buhari tun wọle ni 2019.

Awọn mejeeji gbéná wojú ara wọn ninu ilé nigba ti ọkọ sọ pe o dara ki Buhari maa ṣe ijọb alọ ti iyawo dẹ ni rara, eyi ti Buhari ṣe to, ko pada si Daura.

Abdullahi ni oun ti fibinu ká eyin lẹnu iyawo kí iroyin ija naa to kàn dé ọdọ awọn obi oun.

Gbogbo igbiyanju BBC lati bá Hafsat sọrọ lori iṣẹlẹ yii ja si pabo nitori wọn ni o n gba itọju.

Ibatan rẹ, Ibrahim Suleiman ti BBC ri ba sọrọ ṣalaye pé ọkọ iyawo ti fẹsẹ fẹẹ lẹyin iṣẹlẹ yii ati pe, o ti ni oun kò ni pada sile mọ.

O dabi pe idibo 2019 maa bi ige ati adubi nitori onikaluku lo ni idi to fi n ṣatilẹyin fawọn oludije ọtọọtọ paapaa ninu idle kan ṣoṣo.

Ati pe eyi wu mi, ko wu ọ ni ọrọ naa di bayii laarin ẹbi lori awọn amuyẹ oludije kọọkan.

Bẹẹ, awọn iṣẹlẹ bayii ni awọn mii gba pe o n waye nitori pe awọn oludije mejeeji to n léwájú wa lati agbegbe kan naa ni ariwa Naijiria.