You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Emiliano Sala: 'Kò sí ìrètí pé wọn yóò rí agbábọ́ọ̀lù Cardiff City tó sọnù'
Ko ti i si ireti tabi idaniloju pe wọn yoo ri agbabọọlu Cardiff City, Emiliano Sala, ọkan lara awọn addola ẹmi lo sọ bẹ.
Ọmọ orilẹede Argentina ọhun, to jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati awakọ ofurufu kan lo jọ wa ninu ọkọ baalu naa to deede poora ni erekusu Channel lalẹ ọjọ Aje.
Ọga agba fun ṣiṣe awari loju ofurufu ni Erekusu Channel, John Fitzgerald, sọ pe ''ẹni ti ara a rẹ pe julọ'' ko le lo ju wakati diẹ lọ ninu omi.
Awọn adoola ẹmi tun ti pada bẹrẹ si ni wa ọkọ oju ofurufu naa to poora ati awọn to wa ninu rẹ, lọjọru.
Iroyin kan sọ pe Sala fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si awọn mọlẹbi rẹ lori ẹrọ ayeluja Whatsapp, pe ''ẹru ba oun pupọ.''
Awọn ileeṣẹ iroyin l'orilẹede Argentina jabọ iroyin pe Sala sọ fun mọlẹbi rẹ pe ''Mo wa ninu ọkọ ofurufu kan to dabi ẹni pe o fẹ ẹ jabọ.''
Ni nkan bi aago mọkanla aabọ owurọ l'Ọjọru, ileeṣẹ ọlọpaa ni Guernsey sọ pe ọkọ ofurufu mẹta ati baalu kekere kan wa loju ofurufu, bi wọn ṣe n wa baalu Piper Malibu.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa sọ pe 'awọn ti n ṣayẹwo akọsilẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati mọ boya iranlọwọ kankan le ti ibẹ jade. Ṣugbọn titi di asiko yii, ko ti i si iroyin kankan nipa baalu to poora naa.
Olu ilu orilẹede Welsh ni Sala n lọ lẹyin to buwọlu iwe adehun iṣẹ miliọnu mẹẹdogun Pọun pẹlu ikọ Bluebirds.