You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Arm forces Remeberance day: Naijiria ń ṣe ìrántí àwọn ológun to ṣubú lójú ogun
Òní ni àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọ ogun tói ṣègbé sójú ogun ní Naijiria, àwọn àwọran bí iranti naa ṣe ń lọ ati oun ti àwọn ọmọ Naijria n sọ rèé.
Àwọn ẹgbégun Naijiria gbalejo Aarẹ Muhammadu Buhari ni Eagles Square fun ayajọ ọjọ naa.
Buhari naa yan bi oloogun gẹgẹ bii olori ogun Naijiria.
Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin Agba Bukola Saraki ati abẹnugan Ile Igbimọ Aṣofin Kekere, Yakubu Dogara, naa juba awọn ọmọ ogun to ti ṣegbe ni Eagles Square.
Saraki gbori yin fun awọn obirin ati ọkunrin to n fi ẹmi wọn daabo bo ọmọ Naijiria.
Gomina Ipinlẹ Kaduna, Nasir el-Rufai na ko gbẹyin. O sẹ ẹyẹ fun awọn ọmọ ogun to ti re kọja naa.
Ni Ipinlẹ Delta, Gomina Ifeanyi Okowa naa ṣe iranti awọn ọmọ ogun.
Àwọn oludije fun ipo Aarẹ bii Oby Ezekwesili na ṣe sàdáńkátà sí àwọn ọmọ oloogun.