Kissing: Orílẹ̀-èdè Morocco, Egypt, Zimbabwe, UAE àti China tako títage níta

Kayeefi nla, ile ẹkọ giga fasiti Al-Azhar, lorilẹ-ede Egypt, le akẹkọọbinrin kan kuro nile iwe lẹyin ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa rii nibi ti o ti n di mọ ọrẹkunrin rẹ ninu fidio kan.

Fidio ọhun ṣafihan bi ọrẹkunrin rẹ ti dẹnu ifẹ kọ ọ lori ikunlẹ pe, ṣe yoo fẹ oun ni ọkọ, lẹyin to fesi pe bẹẹni, ni ọrẹkunrin rẹ dimọ gbagi.

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga fasiti Al-Azhar ṣalaye pe, iwa itiju ati abuku ni akẹkọọbinrin naa wu lẹyin to mọ pe, ile iwe ọhun lodi si ki ọdọkunrin ati ọdọbinrin ti wọn ti ṣe igbeyawo maa di mọ ara wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn lorilẹ-ede Egypt nikan kọ ni iru nnkan bayii ti n ṣẹlẹ. Wọnyi ni awọn orilẹ-ede ti ko faye gba a ki ọdọkunrin ati ọdọbinrin ti ko ti se igbeyawo, maa di mọ ara wọn.

Morocco:

Orilẹ-ede Morocco lodi si ki ọkunrin ati obinrin fa ara wọn lọwọ, di mọ ara wọn tabi fẹnu ko ara wọn lẹnu.

Eyi ri bẹẹ nitori ẹsin musulumi ni o jẹ ẹsin kan gbogi ti ọpọ ọmọ orilẹ-ede naa n sin.

Egypt:

Gẹgẹ bi orilẹ-ede Morocco, orilẹede Egypt ko faye gba ki ọkunrin ati obinrin maa fara kan ara lawujọ.

Ẹni to ba dan iru ẹ wo, le foju ba ile ẹjọ labẹ ofin ilẹ naa, koda awọn eeyan yoo doju bo ẹni to ba dan iru rẹ wo.

Zimbabwe:

Ni ile iwe giga fasiti lorilẹ-ede Zimbabwe, o ṣeeṣe ki wọn le awọn akẹkọọ ti wọn ba n fẹnu kora wọn lẹnu tabi ti wọn ba jọ ni ajọṣepọ.

Eleyi lodi sofin ile ọhun, ti ijiya rẹ si le ṣe okunfa ohun ti akẹkọọ yoo fi dero ile.

Dubai, UAE:

Lootọ ni ilu Dubai ti goke agba ṣugbọn ilu naa si tun fofin to de ọkunrin ati obinrin.

Eeyan le dero ẹwọn ti wọn ba ri wọn nibi ti wọn ti n fẹnu ko ara wọn lẹnu, koda ki wọn jẹ tọkọ taya.

China:

Aṣa ati iṣe ilẹ China ko faye gba keeyan maa di mọ ara wọn lawujọ rara.