You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ayajọ iranti awọn akọni: Ayẹyẹ waye kaakiri orilẹede Naijiria
Lọjọ aje tii se ọjọ kẹẹdogun osu kini ọdun 2018 ni ayajọ ọjọ iranti awọn ologun to subu loju ija waye kaakiri tibu-toro ilẹ Naijiria.
Ni ẹkun iwọ oorun guusu awọn ipinlẹ bii Ondo, Ọyọ, Ọsun, Ekiti pẹlu ko gbẹyin ninu sise ayajọ naa.
Ni ipinlẹ Ọsun, Gomina Arẹgbẹsọla to saaju tito ododo soju ẹyẹ awọn akọni ni akoko to latubọ yanana isọkan ati aabo lorilẹede Naijiria.
Gomina ana nipinlẹ naa, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla pe fun atunyẹwo ilana isẹ awọn abọde ologun ti wọn fara jiya loju ija fun isọkan ilẹ Naijiria.
Ni ipinlẹ Ondo, gomina Rotimi Akeredolu ke si awọn agbofinro gbogbo lorilẹede Naijiria lati tubọ ji giri si ipenija ti gulegule wahala awọn darandaran nko ba eto abo.
Ni ipinlẹ Ọyọ, Gomina Ajimọbi dupẹ pupọ lọwọ awọn oloogun ilẹ Naijiria fun diduro sinsin fun isọkan ati alaafia araalu.