JAMB 2019: Wo àwọn ibùdó CBT tó wà nítòsí rẹ

Oríṣun àwòrán, JAMB/FACEBOOK
Ajọ to n ri si idanwo asewọle iwe giga JAMB ti bẹrẹ tita fọọ mu fun awọn ọmọ Naiiria to fẹ ṣe idanwo naa.
Idanwo naa, UTME ti ọpọ maa n pe ni JAMB ni idanwo ti awọn ti awọn to ba fẹ wọ ile iwe giga lorilẹede Naijiria.
Apapọ ajọ to n se agbekalẹ idanwo yii ba ṣe ohun tuntun lọdun yii, wọn fagile fiforukọ ni ibudo cyber cafe ti awọn aṣedanwo maa n lọ tẹlẹ.
Bi fọọmu naa ṣe ti wa jade kaakiri Naijiria fun ẹni to ba fẹ gba, awọn nkankan wa ti ajọ JAMB fẹ ki awọn aṣedanwo mọ eyi ti yoo jẹ ki ilana iforukọ silẹ wọn rọrun.
Agbẹnusọ fun ajọ JAMB, ọmọwe Fabian Benjamin sọ fun BBC pe ẹgbẹrun mẹta abọ Naira (N3500) ni iye owo fọọmu.
Bi o tilẹ jẹ pe aṣedanwo lee nilo lati san ẹẹdẹgbẹrun (N500) ni ibudo CBT gẹgẹ bí owo isẹ ṣugbọn wọn gba aṣedanwo nimọran pe ẹnikẹni ko gbudọ san kọja ẹẹdẹgbẹrin Naira (N700) gẹgẹ bi owo iṣẹ.
Ajọ JAMB sọ siwaju pe lori ẹrọ alagbeka awọn aṣedanwo ni wọn yoo ti kọkọ ṣe iforukọsilẹ ki wọn tilẹ to yọ owo lapo lọ fọọmu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ọfiisi JAMB to ba wa ni ipinlẹ̀ yin naa, ibudo CBT ni".
Bakan naa, ajọ JAMB ti ṣe ọna ti afọju tabi odi lee fi joko ṣe idanwo ọhun.
Ilana lati forukọ silẹ fun idanwo JAMB
Loju itakun agbaye wọn, ajọ JAMB ti ṣe alakalẹ awọn ilana ti eniyan le ṣe lati forukọ silẹ lori ẹrọ alagbeka wọn (iyẹn fun Airtel ati MTN nikan).
- Ẹrọ alagbeka kan ati nọmba kan ṣoṣo ni aṣedanwo lee lo. Kika ọjọ ti o forukọ silẹ, nọmba ẹrọ alagbeka rẹ ati atẹranṣẹ lati ọfiisi JAMB yóò wọle.
Nọmba naa ati orukọ aṣedanwo yoo wa papọ, nitorinaa ma ṣe gbagbe àwọn nkan wọnyi.
- Aṣedanwo yoo nilo lati fi orukọ "[Surname FirstName MiddleName]" pẹlu ifọrọranṣẹ lati ajọ JAMB ranṣẹ si 55019.
- Gbogbo ẹ, ati kikọ ati aaye ko gbudọ ju aaye alifabẹti mejindinlọgbọn lọ (38 characters) bẹẹ si ni aaye gbudọ wa laarin ọrọ meji. Fun apẹẹrẹ: Tinubu Adamu Odemegwu.
- Aṣedanwo yoo wa gba ọrọ aṣiri (profile code) oni alifabẹẹti tabi/ati nọmba mẹwaa (10 characters) gẹgẹ bi atẹranṣẹ lori ẹrọ alagbeka rẹ.
- Aṣedanwo yoo fi ọrọ aṣiri (profile code) naa han nibi to ti fẹ gba fọọmu. Lẹyin naa ni yoo gba atẹranṣẹ "ePIN" lori ẹrọ alagbeka rẹ.
- Eyi ni aṣedanwo yoo fi han ni eyikeyi ibudo CBT ti ajọ JAMB ti fọwọ si fun iforukọ silẹ.
Ẹkunrẹrẹ ilana, ofin ati ikilọ wa ni oriko "download pdf" eyi ti ajọ JAMB ti fi sori itakun agbaye wọn.













