Dino: Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní àwọn mọ̀ọ́mọ̀ gbé Dino ni fún ìtọ́jú níléèwòsàn ìjọba míràn

Awọn ọlọpaa pẹlu iboju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọsẹ to kọja ni ọgbẹni Dino jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpaa.

Awọn ọlọpaa to da aṣọ boju ti ya wọ inu ile iwosan ti Dino Melaye, Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Kogi ti n gba itọju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi awọn to ṣoju wọn ṣe sọ sọ, Ori ibusun alaisan ni aṣofin naa wa ti awọn ọlọpaa naa ti fi tipa tipa mu u lọ wọ inu ọkọ kan ti ko ni nọmba tabi orukọ lara ti wọn si gbe e lọ ibi ti ẹnikẹni ko mọ.

Ọsẹ to kọja ni ọgbẹni Dino jọwọ ara rẹ fun awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn taku si ẹnu ọna ile rẹ to wa ni agbegbe Maitama nilu Abuja fun ọjọ mẹjọ.

Awọn ọlọpaa pẹlu iboju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aburo sẹnetọ ọhun to ba BBC sọrọ pe lootọ ni awọn ọlọpaa wa gbe sẹnetọ naa

Aburo sẹnetọ ọhun to ba BBC sọrọ sọ pe lootọ ni awọn ọlọpaa wa gbe sẹnetọ naa nileewosan ti wọn si ni awọn fẹ gbee lọ si ileewosan ẹka agbofinro ọtẹlẹmuyẹ DSS kan fun ayẹwo miran.

Gẹgẹ bii aburo sẹnetọ naa ṣe sọ, Dino faake kọri pe oun ko ni ba awọn ọlọpaa naa lọ nitori oun ko ni ohunkohun pọ pẹlu awọn agbofinro DSS ki o to di pe awọn ọlọpaa naa fi tipatipa gbee wọ inu ọkọ wọn.

Kini ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Ọlọ̀paa de akoto ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa ni Dino yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii

Amọṣa Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi atẹjade sita pe lootọ ni awọn gbe Sẹnetọ Dino Melaye kuro ni ileewosan ti wọn gbee si tẹlẹ lọ si ileewosan miran to jẹ ti ijọba fun itẹsiwaju itọju rẹ.

Atẹjade naa ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Jimọh Moshood fọwọsi ṣalaye pe iwadii n lọ lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan sẹnetọ naa ati pe ni kete ti iwadii ba pari oun pẹlu awọn afunrasi ọdaran yooku ninu ẹsun naa yoo foju ba ile ijọ.