Ọkọ̀ agbépo gbiná l'Eko

Ọkọ agbepo to n jona naa
Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹrun marundinlaadọta lita epo bẹntiro ni ọkọ agbepo naa gbe lasiko ti ina naa fi suyọ

Ọkọ agbepo kan ti gbina ni agbegbe ogudu ni ilu Eko.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni iwaju ọkọ agbepo naa kan ṣa dede gbina lagbegbe ni agbegbe toll gate.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọ̀rọ̀ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ileeṣẹ LASEMA ni ipinlẹ Eko, Kẹhinde Adebayọ ni ko si ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ọgbẹni Adebayọ ni epo to to ẹgbẹrun marundinlaadọta lita epo disu ni ọkọ akepo naa gbe nigba ti iṣẹlẹ ina naa ṣẹlẹ.

Ọkọ agbepo to n jona naa

Oríṣun àwòrán, LASEMA

O ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ati panapana tete de ibẹ ki o to ṣe ọṣẹ ju bi o ti yẹ lọ.