INEC: Òpómúléró ni ASUU jẹ́ fún àṣeyọrí ìbò 2019

Mahmood Yakubu, olori àjo INEC

Oríṣun àwòrán, INEC

Àkọlé àwòrán, ìfọ́wọ́sowọ́pọ̀ ASUU ló le jẹ́ kí ìdìbò wa ó kẹ́sẹjári

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ASUU ti gba láti kópa nínú ètò ìdìbò ọdún 2019.

Sáájú ní wọn ti ń dágúnla pé àwọn olùkọ́ ati akẹ́kọ́ọ̀ kò ní lè kópa nítorí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọjọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu, alága INEC náà ti kédé pé, àwọn yóò ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ASUU.

Yakubu ni '' Eyi wa láti wa ojúùtú sí ọ̀rọ̀ ìyànṣẹ́lódì tó ń lọwọ́, sùgbọ́n ìpàdé náà kò ní kọjáa ọ̀rọ̀ nípa ìmúrasílẹ̀ fún ìdìbò gbogboogbo tó n bọ̀ nínú oṣù kejì ọdún"

" Ǹkan tó kàn wá jùlọ ní àwọn ipa pàtàkì tí àwọn olukọ tí INEC ti yan ní àwọn Fasiti láti kopa nínú ètò ìdìbò yoo ni.

Asia INEC àti ASUU
Àkọlé àwòrán, ASUU: A ó kópa nínú ètò ìdìbò 2019

A ti ní ìpinu pé ètò ìdìbò náà kò gbọdọ̀ ní kọ́nu-n-kọhọ nítori ìyanṣẹ́lodì àwọn oṣìṣẹ́ Fasiti. ASUU jẹ́ pàtàkì igun ilé fún àjọ wa láti ṣe ètò ìdìbo tó ṣe mú yangan láwujọ àwọn orílẹ̀-èdè.

À ń fojú sọ́nà fún ìpadé ti yóò mú àbájade rere jade wá "

Ẹwẹ̀, ìkéde pé àwọn yóò kopa yìí wáye lọjọ́ Jimọ, lẹ́yìn ìpàdé INEC àti ASUU.