You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Remi Surutu: Tilu - tifọn ni ayẹyẹ ìdána ọmọbìnrin rẹ fi wáyé
Yoruba bọ wọn ni bi ẹkun pẹ titi di alẹ kan, ayọ n bọ lowurọ.
Bẹẹ ni ọrọ igbe aye gbajumọ oṣere tiata lobinrin, Remilekun Oshodi, ti ọpọ eeyan mọ si Remi Surutu ri.
- Kọ́ńdọ̀mù tó bẹ́ gbé iléèṣẹ́ ìjọba àti aládáni kan dé ilé ẹjọ́
- Àgbáríjọ àwọn nọ́ọ̀sì fẹ́ gbé Olamide Baddo lọ sílé ẹjọ́ fún ìbanilórúkọjẹ́
- Gbajúgbajà òṣèré tíátà, "Ijẹwuru" ti jáde láyé
- Ọ̀nà kan ò wọjà fáwọn òṣèré tíátà, bí wọn ṣe ń ta ìpara ìbóra ni wọ́n ń ta aṣọ ẹbí
- Ọkọ̀ wa wọ'gbó lọ lẹ́yìn táwọn dánàdánà dàbọn bò wá- Toyosi Adesanya
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
Idi ni pe ariwo ayọ tun sọ nile rẹ lọjọ Iṣẹgun nigba ti ọmọ rẹ obìnrin, Abiola Ajike, mu ọkọ wale.
Ayẹyẹ idana ọhun lo dun, to si larinrin, ti ọpọ eeyan si n ba yọ ayọ oriire naa, paapaa awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata.
- Ayọ̀ abara bíńtín! Toyin Abraham bí ọmọkùnrin jòjòló
- Saheed àti Fathia Balogun dìjọ ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí, ẹ wo àjọṣepọ̀ tó wà láàrin wọn
- Ẹ́ wo ojú àwọn òṣèré tíátà tó péjú sí Ibadan fún ìpàdé ọlọ́dọọdún
- Àwọn ọmọ Iyabọ Ojo rí Bàbá lẹ́yìn ọdún mẹ́fà
- Mr Latin, Jide Kosọkọ àti Mama Rainbow sọ̀rọ̀ lórí ìjà Toyin ati Lizzy
Surutu to wọ aṣọ funfun lasiko ayẹyẹ idana naa, bi eeyan ba gun ẹṣin ninu rẹ, ko lee kọsẹ rara paapaa nigba to n rọ ojo adura le ọmọ naa lori.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ kinni osu keje ọdun 2017 ni osere tiata padanu ọmọbìnrin kan, ẹni to jẹ alaisi lati ipasẹ arun foniku fọlande.
Awa naa wa n ba Remi Surutu yọ pe o ku oriire idana ọmọ rẹ, ọba oke yoo jẹ ka ri adun pupọ nibẹ