Vaginismus: Nígbà tí ara rẹ bá kọ ìbálòpọ̀, kí ló ṣẹlẹ̀?

Isley Lynn

Oríṣun àwòrán, The Other Richard

    • Author, Nesta McGregor
    • Role, Newsbeat reporter

"Kìí ṣe ìwọ lò ń ṣàkóso bí ara rẹ ṣe ń se. yálà o lọ́wọ́ sí i tàbí o kò lọ́wọ́ sí i. Àwọn olóyìnbó ń pe ọ̀rọ̀ kan ní vaginismus.

Nígbà tí Isley Lynn rántí ìgbà àkọ́kọ́ tó ní ìbálòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́, ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyì tí kò jọ ìgbà àkọ́kọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

"Ó bà mí lọ́kàn jẹ́ púpọ̀. Ó dà bí ẹni pé wọ́n fọ́ mi tútú. Mo dá ẹ̀bi lé ara mi lórí ohun tí kì''i ṣe ẹ̀bi mi.

Nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa lè rántí bí ìbálòpọ̀ àkọ́kọ́ ṣe fún tó tàbí rí bákan bákan, ó jẹ́ ohun tí ènìyàn ò kí ń fẹ́ sọ nípa ti Isley.

Isley ti pe ọgbọ̀n ọdún báyìí sùgbọ́n ara rẹ̀ kò fẹ́ gáánní ǹkan ọmọ ọkùnrin rárá, ìrírí yìí ń fa ọkàn rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó dà bí ẹni tó fẹ́ bò awọ olóógbò ni.

Ẹ̀sà láti inú eré Skin A Cat

Oríṣun àwòrán, The Other Richard

Àkọlé àwòrán, Bí o bá le bò awọ olóógbò, òó mọ bó ṣe rí fún ẹni tí kò fẹ́ kí ǹkan ọmọkùnrin wọ ara rẹ̀.

The NHS sọ ìtumọ̀ vaginismus gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn àgọ́ ara kánmọ́ kánmọ́ sí ìbẹ̀rù ohunkúhun tàbí ohun gbogbo tó fẹ́ wọ ojú ara obìnrin.

Ṣe ni gbogbo iṣan yóò dì pọnpọn tí obìnrin kò sì ní lágbára lórí rẹ̀.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbésí ayé tí kò pariwo ló dára'

Fún ènìyàn tó bá ń ní irú ìrírí yìí, yóò nira láti ki òwú tí wọ́n fi ń dá ìsun ẹ̀jẹ̀ dúró bọ ojú ara rẹ̀, yóò jàa fita fita láti ní ìbálòpọ̀ tàbí kí abẹ́ máà ta á.

Isley ní: "mo gbìyànjú láti lo owù fún dídá ìsun ljẹ̀ dúró nígbà tí mo wà láàrin ọdún kan sí mẹ́wàá, ó kan mí lára gaan bí ẹni pé kò sí ihò lójú ara mi tàbí ògiri dí i pa.

Mo mọ̀ dájú pé ǹkankan ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí mo ní ọ̀rẹ́kùnrin àkọ́kọ́.

òwú tí wọ́n fi ń dá ìsun ẹ̀jẹ̀ dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Yóò nira láti lo òwú tí wọ́n fi ń dá ìsun ẹ̀jẹ̀ dúró

Ọ̀rọ̀ náà ń fa ìpalára gan lórí àwọn ìbáṣepọ̀ Isley. "Mo rántí pé lrù máa ń bà mi pé àwọn ọkùnrin máa ń rò pé mi ò nífẹ̀ẹ́ wọ́n tàbí ọkàn mi kò fà sí wọn.

Ònkọ̀wé yìí ní ìdàmú vaginismus nígbà tó ń súnmọ́ ogún ọdún tí àwọn onímọ̀ nípa ojú ara obìnrin èyí tó mú u tóbi díẹ̀ síi kára lè balẹ̀.

Isley sọ pé lẹ́yìn tí òun gba ìtọ́jú náà ló ríi pé wọ́n ò ṣe iṣẹ́ pé èyí kò sì lè tán ìṣòro àìnídùnú rẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́.

Doctor treating a patient

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Treatment for vaginismus includes psychosexual therapy and relaxation techniques

Onímọ̀ nípa ara míìràn ló bi mí wí pé kí ni mo fẹ́ gaan láti dá lára.

Ọ̀rọ̀ náà ló wà ní ìparí ìwé tó kọ níbi tí wọ́n ti ní kí òṣèré náà sàlàyé ohun tó fẹ́ nípa ti ìbálòpọ̀.

Ìgbà náà ló mọ̀ wí pé òun kò nílò láti ní ìrírí ìbálòpọ̀ bíi gbogbo ènìyàn.

"Wí pé, kọ ìtan tìrẹ láyé kí o sì ṣe ohun tó le mú inú ara rẹ̀ dùn."

A couple in bed

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library

Bí ohunkóhun nínú ọ̀rọ̀ yìí bá ń bí ọ nínú, o leè rí ìmọ̀ràn tó wúlò lójú èwèBBC Advice fún ìmọ̀ràn.

Ó nira láti lè sọ iye obìnrin nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń jìyà vaginismus bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwádìí kan fihàn wí pé ọ̀kan nínú mẹ́wàá obìnrin wọn ni kìí gbádùn ìbálòpọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí ló ń fa èyí, vaginismus kàn jẹ́ ọ̀kan lára wọn ni.

"Vaginismus yàtọ̀ sí kí ìbálòpọ̀ máa dun èèyàn nítorí ìdáhùn ara ló fà a gẹ́gk bí Dókítà Vanessa Mackay tó jẹ́ oníṣègùn òyìnbó nípa obìnrin ní ilé ìwòsàn ọm ọbabìnrin Elizabeth ní Glasgow.