Ejò Sebe, Ọká, òjòlá àti àkeèké jẹ́ alábagbé Phillipe
Ali àti Gator jẹ́ ìbejì ọọ̀nì ti Phillipe jọ wà ninu iyàrá.
Àwọn alantakun to tobi pupọ jẹ ohun iṣere fun Phillipe Gillet to jẹ ọmọ ilẹ̀ Faranse.
Awọn eniyan Yoruba gbà pe inu igbo ni èranko afayafa n gbé ati pe wọn lewu pupọ.
Awọn ogboju ọdẹ nikan lo le mu wọn looyẹ afi ti àwọn omode ba tun ni oore ọfẹ lati lọ wo wọn ni ọgba ẹranko.