Talàwọn ọmọlẹ́yìn Saraki tó ń du ipò Gómìnà ní Kwara?

Aworan Awọn oludije PDP fun ipo Gomina ni ipinlẹ Kwara
Àkọlé àwòrán, Ali Ahmad,BolajjiAbdullahi,Zakari Mohammed ati Aliyu Ahman Pategi wa lara awọn oludije fun ipo Gomina labẹ ẹgbẹ PDP

Ọrọ oselu ipinlẹ Kwara n polukuu musu ni lọọlọ yii paapa julọ nipa ẹni ti yoo jawe olubori lati soju ẹgbẹ PDP ninu idibo Gomina ni ipinlẹ naa.

Ti a ba ni ki a ma ka wo o ni eni eji,o kere tan oludije maarun to jẹ ọmọlẹyin Aarẹ ile asofin agba Bukola Saraki lo ti fi erongba silẹ lati soju ẹgbẹ PDP.

Bolaji Abdullahi to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu APC teleri wa lara awọn to sẹsọẹ kede erongba lati du ipo naa.

Aworan Bolaji Abdullahi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bolaji Abdullahi

Àkọlé àwòrán, Bolaji Abdullahi nibi ikede iferongba lati dije Gomina

Ni ọjọru ni o kede erongba rẹ ni Ilu Ilorin niwaju awọn alatilẹyin rẹ.

Bakan naa la gbo pe Zakari Mohammed to jẹ asoju fun Baruten Kaima ni ẹkun ariwa ipinlẹ Kwara naa fi iwe iferongba rẹ sowo si ile ẹgbẹ PDP, iyẹn Wadata House, labuja lọjọru.

Aworan Zakari Mohammed

Oríṣun àwòrán, @HonZakari

Àkọlé àwòrán, Zakari Mohammed naa ti fi iwe ferongba sowo si oul ile ẹgbẹ PDP labuja

Bi a ko ba gbagbe, olori ile asofin ipinlẹ Kwara Ali Ahmad naa ti saaju kede erongba rẹ lati du ipo Gomina ipinlẹ Kwara labẹ asia PDP.

Gbogbo awọn ti a ka sile yii to fi mọ Ahmad Pategi to jẹ ọmọ ile asojusofin agba fun Edu/ Moro/Patigi ni ẹkun ariwa Kwara naa ko gbeyin .

Aworan Ahman Pategi

Oríṣun àwòrán, @fatimah_jiyah

Àkọlé àwòrán, Aliyu Ahman Bahago Pategi naa ko gbẹyin ninu idije to wa nilẹ yi

Ta ni yoo ja mọ lọwọ

Ti a ba fi bi nnkan ti se ma n sẹlẹ lateyin wa wo,Bukola Saraki to jẹ Baba Isale fun awọn oloselu ipinlẹ Kwara a ma yan oludijk kan laayo leni ti awn oludije to ku yoo si gbaruku ti ninu idibo.

Sugbọn bayi ti o j wi pe Bukola Saraki naa n du ipo Aarẹ orileede Naijiria o le ma rọrun lati mu eeyan kan.

Aworan Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán, Temi to mi lẹru.Bukola Saraki naa n dije ipo Aarẹ Naijiria

Ti a ba tun wo wi pe gbogbo awọn to n du ipo yi naa ni wọn ti n ba Bukola Sraki se po ti pe.yoo soro ki o to le so wi pe ohun mu eeyan kan ti o j aayo rẹ.

Lafikun,awọn amoye kan ni sisi ipo pada lati inu ẹgbẹ APC lo si PDP le fe se idiwọ fun awọn oludije yi nitori o ni awọn kan to wa ninu gbẹ PDP tele ti awn naa f du ip Gomina nipinlẹ Kwara.

Lara wọn lati ri ojọgbọn Shuaib Oba Abdulraheem to o fi igba kan jẹ Alakoso Yunifasiti ilu Ilorin.

Kini ''Zoning'' ni se pẹlu ọrọ to wa nilẹ yi.

Awọn oloselu Kwara a ma saba seto pipin ipo oselu laarin awn ẹkun idibo to wa ni ipinlẹ naa.

Nigba ti nnkan to di dojuru to bayi,ẹkun kan ni yoo fa Gomina kale ti awọn ẹkun miran naa yoo si di ipo miran mu gẹg biigbakeji tabi Minisita ninu ijọba apapọ.

Abdulfatai Ahmed to jẹ Gomina kẹyin nipinlẹ Kwara wa lati ẹkun idibo Guusu Kwara.

Aworan ikede FATAI Ahmed loju opo Twitter

Oríṣun àwòrán, @AbdulfataAhmed

Àkọlé àwòrán, Gomina Fatai Ahmed n gbero lati lo ile asofin agba lẹyin saa rẹ gẹgẹ bi Gomina

Bukola Saraki to jẹ Gomina saaju ri wa lati ẹkun gbungbun Kwara.

Awọn kan n sọ wi pe ni bayi, ẹkun idibo ariwa Kwara lo kan lati yan Gomina sugbọn ko si ẹni to le so pato boya adehun yi le di mimusẹ.

Idibo abẹnu ẹgbẹ PDP ni yoo yanju ọrọ yi sugbọn kko to di igba naa o seese ki awọn oludije ma se idunadura lori ni ti yoo jọwọ ipo naa ati ẹni ti wn yoo gbaruku ti lati jawe olubori ninu idibo to n b lọna.