Àwọn ọ̀dọ́ lu 'Ẹja' tó fi mọ́tò pa ọ̀dọ́kùnrin kan pa

Awọn ero ati ọkọ akẹkọọ naa

Oríṣun àwòrán, florbabs

Àkọlé àwòrán, Wọn ni o ti kọkọ fi ọkọ rẹ kọlu obinrin ẹlẹha kan lagbegbe Olowo-Bida nilu Ẹdẹ kan naa

Awọn eeyan ilu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun tu lu ọmọ ileewe onipele kẹrin ileewe giga gbogbońṣe apapọ to wa ni ilu naa pa.

Eyi ṣẹlẹ lẹyin to fi mọto pa akẹkọọ kan ti o n wa ọna ati wọ ileewe naa.

Akẹkọọ naa ti inagijẹ rẹ̀ ń jẹ 'Ẹja' ni wọn sọ pe o n kẹkọọ imọ nipa ile kikọ nileewe gbogboniṣe Polytechnic to wa nilu Ẹdẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹni to lee sọ ni pato iye ẹmi to lọ sii, awọn olugbe adugbo Ita Oloki nilu Ẹdẹ ni eeyan mẹrin lo tun ku yatọ si akẹkọọ to n wa ọna ati wọle si ileewe naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni eeyan kan ṣoṣo ni ọkọ̀ arakunrin naa gba.

Gẹgẹ bi iroyin ti sọ, awọn ọdọ ilu Ẹdẹ ti inu n bi ni wọn lu arakunrin naa pa lẹyin ti wọn ni ere aṣapajude to n fi ọkọ rẹ sa nigba to n gbiyanju ati sa bọ mọ agbofinro lọwọ.

Wọn ni o ti kọkọ fi ọkọ rẹ kọlu obinrin ẹlẹha kan lagbegbe Olowo-Bida nilu Ẹdẹ kan naa.

Irọlẹ ọjọ Aje ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ eleyi to ti sọ ilu iṣẹmbaye naa sinu ọfọ nla.

Àkọlé fídíò, Bọde George: Àwọn èèyàn mọ ẹni to yìnbọn pa Adeniyi Aboriṣade
Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi
Àkọlé fídíò, 'Mi o fẹẹkan ni mo fẹ dupo aarẹ'