Saraki, Dogara: Buhari gbọdọ̀ kìlọ̀ fún àwọn ọlọ́pàá lórí ọ̀rọ̀ Benue

Oríṣun àwòrán, @nassnigeria
Aarẹ Ile Aṣofin Agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki ati Olori Ile Aṣoju Aṣofin, Yakubu Dogara ti koro oju si igbesẹ to n waye ni ile aṣofin ipinlẹ Benue, eleyi ti wọn ṣe akawe rẹ gẹgẹ bii " dida ẹgbin si ibi mimọ eto iṣofin"
Awọn aṣofin mẹjọ ninu ọgbọn aṣofin to wa nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Benue bẹrẹ igbesẹ ati yọ gomina ipinlẹ, Samuel Ortom nipo lẹyin ti wọn se awọn aṣofin mejilelogun yoku mọ ode gbagede ile aṣofin ipinlẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu atẹjade kan ti Saraki ati Dogara jumọ fọwọ si, wọn ke si aarẹ Mohammadu Buhari lati ke si ileeṣẹ ọlọpaa pe ko tọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ, ki wọn si yee sọ ara wọn di ohun elo fun dida ilana iṣejọba tiwantiwa ru.

Oríṣun àwòrán, Benue News
"A ti boju wo ohun to n lọ nipinlẹ Benue daradara nibi ti olori ile naa tẹlẹ ti wọn ti rọ loye, Terkimbir Ikyange ko awọn aṣofin meje miran sodi lati fi iwe iyọninipo ranṣẹ si Gomina Samuel Ortom, nigba ti ti wọn ko faaye gba awọn aṣofin mejilelogun ti wọn pọ julọ ninu ile naa lanfani ati wọ gbagede ile aṣofin ipinlẹ ọhun. A gbagbọ pe iwa arufin patapata ni eyi ko si ba ilana ti ofin la kalẹ fun awọn aṣofin lati gunle fun yiyọ gomina mu."
"Bakan naa ni o tun jẹ iyalẹnu pẹlu ipa ti awọn ọlọpaa n ko ninu ilana arufin yii. Igbagbọ wa ni pe, ẹka aṣofin ni wọn n ta ẹrẹ ba lori ọrọ yii.
Eyi si tun ṣe akawe bi wọn ṣe n lo ọlọpaa lọna aitọ lati fun ọrọ oṣelu lorilẹede yii."








