Wàhálà Bódìjà: Ẹ̀mí bọ́ nígbàtí alápatà àti ọlọ́pàá wọ̀já ìjà

Ajoku taya loju titi
Àkọlé àwòrán, Àwọn alápatà takú láti tẹ̀lé àsẹ ìjọba pé kí wọn kó lọ sí ọjà ẹran tuntun, àmọ́ tí wọn yarí

Àwọn alápatà ti takú láti tẹ̀lé àsẹ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pé kí wọn kó lọ sí ọjà ẹran tuntun, àmọ́ tí wọn yarí.

Ìdí nìyí tí ìjọba se kó àwọn ọlọ́pàá lọ sí ọjà Bódìjà láti pé wọn tẹ̀lé àsẹ ìjọba, sùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ náà bọ́wọ́ sórí.

A gbọ́ pé ẹ̀mi méjì ló bọ́ lásìkò táwọn alápatà àti ọlọ́pàá wọ̀já ìjà, tí rògbò-dìyàn sì gbòde ní ọjà náà.

Abawọle ọja Bodija
Àkọlé àwòrán, A gbọ́ pé ẹ̀mi méjì ló bọ́ lásìkò táwọn alápatà àti ọlọ́pàá wọ̀já ìjà, tí rògbò-dìyàn sì gbòde ní ọjà náà.

Níbáyìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ti ọjà Bódìjà pa.

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba de sibi isẹlẹ naa, a ri pe awọn eeyan kan ti dana sun aloku taya ọkọ loju popo, ti ọpọ eeyan si duro go go go niwaju ẹnu ọna abawọle ọja naa.

Ọ̀kan lara àwọn ontaja ni ọja Bodija to ba ileesẹ wa BBC sọrọ salaye bi isẹlẹ naa se waye.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Wàhálà Bódìjà: Àwọn alápatà àti ọlọ́pàá wọ̀yá ìjà

Koda, a gbọ pe diẹ ninu awọn alapata naa ti lọ si ibudo tuntun ti ijọba si fun wọn, ti awọn to fi aake kọri, lati lọ si ọja tuntun naa, si n fi apa janu.

Nigba to n salaye idi ti ijọba fi gbe ilẹkun ọja naa ti, alaga agbegbe idagbasoke ti A Aarẹ Latoosa, ti ọja Bodija wa labẹ rẹ, Adekunle Ọladeji, salaye pe ijọba fẹ dena ofo ẹmi ati dukia lo mu ko gbe ilẹkun ọja naa ti pa.

Ẹran ti awọn Alapata fi silẹ salọ
Àkọlé àwòrán, Ọladeji ni alaafia ti n pada jọba ni agbegbe Bodija bayii.

O ni ijọba ko tun fẹ ki ọwọja rogbodiyan naa tan ka awọn agbegbe miran ni ipinlẹ Ọyọ, ni wọn se ti ọja Bodija.

Ọladeji ni alaafia ti n pada jọba ni agbegbe Bodija bayii.

Akọroyin wa ri pe n se ni awọn alapata naa fi awọn ẹran wọn silẹ, ti wọn si salọ.