Oshodi-Oke: Kò dára báwọn òsèré se ń fi dúkìá sakọ

Oríṣun àwòrán, Ronkẹ Oshodi-Oke
Ronkẹ́ Oshodi-Oke ní ohun tí kò dara, kò dára ni, bí àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ òsèré tíátà se máa ń fi dúkìá tí wọn bá sẹ̀sẹ̀ rà, bíi ilé àti mọ́tò, se bùgá lórí òpó ìkànsíra-ẹni.
Ó ní ilé làá wò, ká tó sọ ọmọ ní orúkọ̀, nítorí náà, ó yẹ káwọn òsèré náà máa kọ́kọ́ se àkíyèsí inú ilé tí wọn ti jáde wá, kí wọn tóo máa se yàǹga lórí ìtàkùn àgbáyé.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"Sé wọn rí òsìsẹ́ ilé ìfowó-pamọ́ (Banker) kankan, kó máa se àfihàn mọ́tò àbí ilé wọn lórí afẹ́fẹ́?, sùgbọ́n àwọn akẹẹgbẹ́ mi yóò ra mọ́tò lásán, wọn yóò máa gbé wá sórí ayélujára, kódà, ẹnití kò tíì tó ogójì ọdún náà yóò máa polongo pé òun ń se ọ̀jọ́ ìbí ogójì ọdún. Bí wọn sì tún ra ilé náà, wọn yóò máa gbe wa sórí afẹ́fẹ́, Kín ló dé ?"
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ronkẹ Oshodi-Oke wá ń bèèrè pé kín ni wọ́n ń se èyí fún? "Ọdúnladé Adékọ́lá ra ọkọ̀ Range Rover, kò sẹ́ni tó gbọ́ síi, nítorí pé ó gbọ́n, ó sì ní ọpọlọ ni. Bí Lámọ́ín bá ra mọ́tò, ó di orí ayélujára, bí làkásègbè bá ra ilé, ó di orí ìtàkùn àgbáyé, se orí afẹ́fẹ́ ni èèyàn ti ń se ilé ayé ni ?"
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2

End of Instagram post, 3
Bẹ́ẹ̀ bá sì gbàgbé, ọ̀pọ̀ àwọn òsèré orí ìtàgé ni wọ́n fi dúkìá tí wọn sẹ̀sẹ̀ rà se yàǹnga lórí ayélujára. Lára wọn ni Mercy Aigbe tó ra ilé, tó gbe sí orí ìtàkùn àgbáyé àti Nkechi Blessing, tó sẹ̀sẹ̀ ra ọkọ̀ Toyota Venza pẹ̀lú Ọlátáyọ̀ Amọkade, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ìjẹ̀bú, tóun náà ra ọkọ̀ kan.

Oríṣun àwòrán, Ronkẹ Oshodi-Oke